Mọ̀ síi nípa Oyedele Adedokun tó ya àwòràn Donald Trump tó lu ayélujára pa

Image copyright @Dok
Àkọlé àwòrán Oriṣii nkan daadaa ni a le fi ayelujara ṣe ni rere, kii ṣe fun iwa ibajẹ nikan.

Ọdọmọkunrin ayaworan ọmọ Naijiria kan, Isaac Oyedele Adedokun to ya aworan aarẹ ilẹ̀ America, Donald Trump ni iroyin nipa rẹ ti lu ayelujara pa.

Oyedele ti gbogbo eeyan mọ si doks_art lẹnu iṣẹ rẹ lo fi kalamu ya aworan aarẹ Trump to wa kede lori ayelujara pe oun fẹ ki awọn eeyan ba oun pin in titi Trump a fi rii.

Image copyright @dok
Àkọlé àwòrán Eyi ni lara awọn iṣẹ ti Oyedele n joko ti lati fi gbe awọn ọdọ sita

Ni kete ti iroyin yii tan de ọdọ Aarẹ Trump ni oun naa ti da Oyedele lohun to gboriyin fun un pe, iṣẹ gidi lo ṣe.

Oyedele ni odiwọn aworan naa to 24 X 21 ni eyi to lo to wakati aadọrin lati fi ya.

Tani Oyedele Adedokun?

Oyedele Adedokun Isaac ni orukọ ọdọmọkunrin ayaworan yii

Oun funra rẹ lo kọ ara rẹ ni iṣẹ ayaworan, ko kọọ nibi kankan rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

Oyedele jẹ ayaworan to n fi kalamu da ara to ba wuu ti awọn eniyan si n kọ Haa le lori nigbakigba ti o ba gbe aworan naa kalẹ bii ti Donald Trump yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

Oyedele ni awokọṣe awujọ lo maa n jẹ iwuri lori nkan ti ohun ba fẹ ya pẹlu kalamu oun.

Ati pe ko si nkan naa to munilọkan ti oun ko le ya pẹlu kalamu oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀbẹ̀wò Macron: Iṣẹ́ Fela kò le parẹ́

Bakan naa ni Oyedele ni ipenija to n koju awọn ọdọ Naijiria maa n jẹyọ ninu iṣẹ oun loorekoore.

Oyedele ni aworan Trump to lu ayelujara pa yii ni ikeji iru rẹ ti oun maa fi ya aarẹ ilẹ̀ America.

Image copyright @doks
Àkọlé àwòrán Okan lara awon ise akanse ti Oyedele ti se lati safihan awon ipenija to n koju odo Naijiria

Messi ló gb'àmì ẹ̀yẹ Ballon D'or lóòtọ́ọ́, àmọ́ Ronaldo ló dára jùlọ (GOAT)- Mendes

Ilé ẹjọ́ Eko pàṣẹ, EFCC mú u ṣẹ, Ìjọba gbẹ̀sẹ̀ lé ilé Saraki ní Ilorin

Kí ni pàtàkì ọ́fíìsì agbègbè fún aṣòfin?

Nǹkan mẹ́wàá tó yẹ ní mímọ̀ nípa fásitì ẹ̀kọ́ ìrìnnà òní $50m ní Nàìjíríà

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWaris Kareem: Emmanuel Macron kan sáárá lórí àwòrán tó yà