WorldDisabilityDay: Ọdùn n dùn fáwọn àkàndá ẹ̀dá ni Akurẹ lónìí

Àkọlé àwòrán Bi awọn kan ṣe n gbe ẹru to wuwo lawọn miran n sare lori papa ti onikaluku n fayọ rẹ han

Ajọ Differently Abled Foundation ati ajọṣepọ awọn ajọ aranilọwọ miran ti kii ṣe ti ijọba ni wọn n ṣeto sisami ayajọ ọjọ awọn akanda ẹda lagbaye tọdun 2019 ni ilu Akurẹ ni ipinlẹ Ondo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

Papa iṣere tilu Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo ni eto naa ti n lọ lọwọ ni eyi gbogbo awọn ololufẹ akanda ẹda peju pese si lati wa ṣe koriya fun wọn.

Àkọlé àwòrán Awọn akanda ẹda kan ni yii ti wọn kopa ninu idije bọọlu ẹyin lori tabili ni Akurẹ

Oriṣiriṣi aworan ni akọroyin BBC, Dayọ to ba wọn peju sibẹ naa fi ranṣẹ lati fi ṣafihan ayọ awọn akanda ẹda to n sami ọdun wọn lonii.

Àkọlé àwòrán Ko si ere yii ti awọn akanda ko le kopa ninu rẹ, ọna ara kan ni awọn maa n gba kopa ninu rẹ fun igbadun wọn ni
Àkọlé àwòrán Odiwọn ẹru wiwo yii gan an jẹ eyi ti awọn abarapa miran ko le gbe bi wọn ṣe da pe to.

Awọn miran ti wọn peju pesẹ si papa iṣere Akurẹ ni awọn aṣoju ijọba Ondo, awọn ẹgbẹ oniṣowo loriṣiiriṣii ti wọn ba wọn n dunnu ọjọ oni.

Àkọlé àwòrán Sisun silẹ gbe ẹru wiwo naa wa lara idije ara ọtọ ti wọn n kopa ninu rẹ ni Akurẹ
Àkọlé àwòrán Awọn miran niyii ti wọn n kopa ninu idije gbigba igi lọwọ ara ẹni ninu ere sisa

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC ati awọn ẹgbẹ awakọ NURTW ẹka ti ipinlẹ Ondo naa ba wọn kopa ninu eto naa ni Akurẹ.

Àkọlé àwòrán Tarugbo tomidan, tọkunrin tobinrin to jẹ akanda ẹda ni wọn lọ si papa iṣere Akurẹ lati ọ kopa nibi eto akanṣe toni naa

Fola ṣalye pe ko sẹni to wu lati ya akanda bẹẹni ko ẹbi ti ko le bi akanda ẹda, ṣugbọn itọju lo ṣe pataki ju.

Àkọlé àwòrán Aaya bẹ silẹ, o bẹ sare ni ọrọ idije naa di ni papa iṣere Akurẹ laarin awọn ipele akan da loriṣiiriṣii

Fọlajogun Akinlabi to jẹ adari ajọ Differently Able Foundation sọrọ kikun nipa oriṣii awọn ipenija to n koju awọn akanda ẹda bẹrẹ lati lilo ile ifowopamọsi.

Àkọlé àwòrán A ju ara wa lọ; ijakadi kọ ni ọrọ awọn idije to n waye loni nibi ayajọ ọjọ awọn akanda ẹda ni papa iṣere Akurẹ

Kò sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ mọ lópópóna márosẹ̀ Eko si Ibadan

Erin mẹ́fa wó níbi tí wọ́n ti fẹ́ dóòlà ẹ̀mí ara wọn

Àwọn agbébọn pa ènìyàn mẹ́rinlá lásìkò ìjọsìn

Kò sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ mọ lópópóna márosẹ̀ Eko si Ibadan

Àkọlé àwòrán Ipele ere sisa miran tun ni eleyii ti awọn ọkunrin nikan kopa ninu rẹ lati fi ọna àmúrìn wọn han

Eto ti wọn ṣe ni papa isere Akurẹ naa fun awọn akanda ẹda ni anfani lati so awọn ipenija ti wọn n koju fun ijọba ati awọn ara ilu.

Àkọlé àwòrán Awọn akanda kan ni awọn adari eto n to yii ṣaaju idije tiwọn lati fi ṣe koriya pe ko si nkan to wu wọn ti wọn ko le ṣe pẹlu ilana miran
Àkọlé àwòrán Awọn miran pẹlu ajọ Washington to n pese iranlọwọ ni wọn n yan bi ologun nibi eto naa ni Akurẹ

Arabinrin Folasade Ariṣe to jẹ aṣoju ijọba Ondo fun awọn akanda ẹda naa sọrọ lori ọna abayọ kan si iṣoro awọn akanda.

Eyi lo pe ni amuṣẹ ati ifẹsẹmulẹ ofin didẹyẹsi awọn akanda ẹda lawujọ, nibi iṣẹ, ninu ile laarin ọkunrin si obinri ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé àwòrán Awọn aknada miran ni wọn n gba igi ere sisa lọwọ ara wọn bayii
Àkọlé àwòrán Yiyan bii ologun lori kẹkẹ fawọn to n loo naa waye nibi eto naa ni Akurẹ ki gbogbo eeyan to wa nibẹ le kopa bo ti yẹ.

Ọrọ ideyẹsi awọn afin naa tun jẹyọ gẹgẹ bii akanda ẹda ti awọn eniyan mii maa n yago fun wọn bii pe wọn ni arun lara.

Alaga awọn Afin ni Ondo, ọgbẹni Ayọdele naa sọrọ lori ohun ti oju wọn n ri tọ.

Àkọlé àwòrán Awọn akanda ọkunrin naa sa ere idijẹ Akọni ni mi nibi eto naa ni papa iṣere ni Akurẹ

Bakan naa ni wọn tun gab awọn aknada ẹda nimọran lati sa ipa lati bori ipenija wọn laiṣe ọlẹ ati pe ki ẹbi, ara, ọrẹ ẹnikẹni to jẹ akanda maa pese iranlọwọ to yẹ fun wọn loorekoore.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA