Pákó ni bàbá mi ń tà ní Bodija, mo dúpẹ́ '1st class' mi- Habibat
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

UI graduation: Fasiti Ibadan ló fún mi ni ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí mo fi kàwé síi- Habibat

Mo pinnu lati kawe gba ẹkọ ọfẹ ko le rọ baba mi lọrun sii- Habibat

BBC Yoruba n fẹ ki awọn ọdọ ọmọ Oodua tubọ jẹ awokọṣe rere fawọn eeyan kaakiri agbaye ni.

Habibat Olayinka Owolabi ni ọkan ninu awọn akẹkọọ fasiti ọlọgba ẹranko ti Ibadan mẹta to gba aami ẹyẹ to pegede julọ ni saa eto ẹkọ tọdun 2019.

Loṣu kọkanla ti fasiti Ibadan nibi ti sanmọnti gbe dun ilẹ̀ ṣe ayẹyẹ fawọn akẹkọgboye jade ni Habiba ti ṣe ipo keji ninu awọn mẹta to fakọyọ naa.

Habibat sọrọ lori igbiyanju awọn obi rẹ nigba to rọrun ati igba to ku diẹ kaato nidi iṣẹ pako ti wọn n ta.

O fi imoore rẹ han si fasiti Ibadan to fun un lẹbun ẹkọ ọfẹ to fi kawe pegede bayii.

Ojọgbọn Oluṣọla Oyetunji to jẹ adari ẹka ẹkọ nipa eweko, iyẹn Botany ti Habibat ti ṣetan ṣapejuwe rẹ ni ọmọ to ni itẹriba ati iwa irẹlẹ pupọ.

Eyi fihan pe iwa rere naa ṣi lẹṣo eniyan lasiko yii lainiifiṣe ipo ti ẹda ba wa laye.

Aliyu Adisa Owolabi to jẹ baba Habibat to n ta pako ni ọja Bodija naa ṣalaye ìbí Habibat pe, lati inu oyun lo ti hande pe akanda ẹda ni iya rẹ fẹ bi.