Serap àti Senate Pension: Sẹ́nátọ̀ àti Gómìnà àná, ẹ dá owó ìfẹ̀yìntì yín padà sápò ìjọba- Adájọ́

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Wo diẹ lara awọn Gomina ti ile ẹjọ ni ki wọn da owo ifẹyinti ti wọn ti gba tẹlẹ pada

Ilé ẹjọ giga ni Ikoyi ni ipinlẹ Eko ti da ẹjọ ẹ da owo pada fawọn aṣojuṣofin to n gba owo ifẹyinti.

Ile ẹjọ Ikoyi da ẹjọ ti ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ati iṣẹ akanṣe ti a mọ si Socio-Economic Rights and Accountability Project (SERAP) gbe lọ sile ẹjọ naa.

Awọn SERAP lo kede ayọ loju opo twitter wọn pe idajọ yii tẹ dara lasiko yii.

Lati ọdun 2017 ni SERAP ti pe ẹjọ naa lori bi awọn gomina to ti jẹ ri ti wọn n gba owo ifẹyinti ti wọn tun n gba owo oṣu senatọ ati minista.

Bakan na ni SERAP gbe ijọba lọ sile ẹjọ pe wọn kuna lati gba owo to to ogoji biliọnu naira ti awọn gomina to ti di minista ati senetọ bayii ṣi n gba gẹgẹ bii owo ifẹyinti

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSERAP gba ìjọba apapọ̀ nímọ́ràn láti tún ẹ̀rí kó jọ́ lórí Saraki

Diẹ lara awọn ti SERAP fẹsun kan ni Rabiu Kwakwanso, Theodore Orji, Abdullahi Adamu, Sam Egwu, Shaaba Lafiagi, Joshua Dariye, Jonah Jang, Ahmed Sani Yarima, Danjuma Goje, Bukar Abba Ibrahim, Adamu Aliero, George Akume, Biodun Olujinmi, Enyinaya Harcourt Abaribe, Rotimi Amaechi, Kayode Fayemi, ati Chris Ngige.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAjọ SERAP sọrọ lori owo ifẹhinti awọn oloselu kan

Ile ẹjọ paṣẹ pe ki Abubakar Malami to jẹ adari eto idajọ Naijiria lati gbe igbesẹ to yẹ lati rii pe eyi ko waye mo ki ẹni kan maa gba iru owo gọbọi bayii lowo ifẹyinti ki wọn tun maa gba owo oṣu gẹgẹ bii senetọ abi minista.

Ile ẹjọ sun imuṣẹ igbẹjọ naa si ọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun 2020 lati fi mọ boya akọsilẹ ti wa pe ijọba apapọ atawọn mu idajọ yii ṣẹ bo ti yẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionUI graduation: Fasiti Ibadan ló fún mi ni ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí mo fi kàwé síi- Habibat

Laipẹ nile igbimọ ipinlẹ Zamfara gbẹse le ofin to ni ki wọn maa san owo ifẹyinti fawọn gomina ati igbakeji wọn ati awọn owo ajẹmọnu miran.

Ajọ SERAP ni awọn yoo tẹsiwaju lati maa gbe igbesẹ to yẹ titi gbogbo awọn ti ọrọ kan a fi tẹle aṣẹ ofin ile ẹjọ.

Ati titi awọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ kọọkan a fi gbẹsẹ le ofin sisan owo ifẹyinti ati ajẹmọnu awọn gomina ipinlẹ wọn titi aye