Teni entertainer: Idi ti mí kìí fi ṣí ìhòhò mi bi àwọn olórin obinrin míran

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTẹniọla: Pè mí láago tí o bá mọ iyán gún pẹ̀lú ọbẹ̀ ilá tó dùn

Yoruba bọ wọ́n ni bí fingbáfingbá kò bá fingbá mọ, èyi to tí fin silẹ̀ kò ni parún.

Tení Apata ti gbogbo ènìyàn mọ si Teni Entertainer ti pari ayẹyẹ orin to fẹ́ ṣe sùgbọ́n ǹkan to jẹ́yọ lásìkò àyẹyẹ náà kò tan nilẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọlólùfẹ́ Teni lórí àtẹjiṣẹ́ twitter lo ti n yin Tẹ́ni pàápàá jùlọ lóri ìmúra rẹ lásikò àyẹyẹ náà àti ní gbogbo ìgbà.

Image copyright Teni
Àkọlé àwòrán Teni: Idi ti mí kìí fi ṣí ìhòhò mi bi àwọn olórin obinrin míran.
Image copyright Empics
Àkọlé àwòrán Tenientertainer: Olórin obìnrin tí kìí ṣi ìhòhò rẹ silẹ̀- Olólúfẹ Teni

Ọ̀rọ̀ yìí wá di gbigbà bi ẹni gba igbá ọti nígba ti @Benita_Fairy kọ pé Teni fí han pé àwọnn obinrin ọlórin lé ṣe àṣeyori lái ṣí ìhòhò wọ́n sílẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIná PHCN tó dé lójijì ṣàkóbá ńlá ní Ibadan

Ní kété to sọ èyí tan ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ si ni gbàá bi ẹni gba igbá oti, bi àwọn kan ṣe ni kìí ṣe ]oun nikan ni kìí ṣí ìhòhò rẹ̀ sílẹ̀ ní àwọn míràn ni iṣe ọkunrin lo n ṣe ni kìí ṣe ṣi ara silẹ̀,

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa
Image copyright Oba Orin
Àkọlé àwòrán Teni: Olórin obìnrin tí kìí ṣi ìhòhò rẹ

Sáàju ni Teni Apata lásìkò to ṣe àbẹ̀wò si ilé iṣẹ́ BBC ti sàlàyé ìdí ti kìí fi ṣi ìhòhò rẹ̀ silẹ̀ nígba gbogbo

Teni sàlàyé pé níní ifẹ́ si ominira ara òun jẹ́ ọkan pàtakì idí ti òun kìí fi ṣi ìhòhò ara òun sílẹ̀.

Image copyright IamDayo
Àkọlé àwòrán Tenientertainer: Olórin obìnrin tí kìí ṣi ìhòhò rẹ silẹ̀- Olólúfẹ Teni

Ọpọlọpọ lo n sọrọ lori ayelujara pe awokọṣe to yẹ ki awọn ọdọbinrin iwoyi maa wo ni Teni jẹ nitori pe eyi fihan pé ko si nkan ti o ko le da laye ti Olorun ba ti gab funẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya