Mama Rainbow: Ta lọ ń fi orúkọ Mama Ranibow gbowó gan-an?

Iya Rainbow Image copyright MamaRainbow
Àkọlé àwòrán Mama Rainbow: Ta lọ ń fi orúkọ Mama Ranibow gbowo gan-an?

Gbajúgbajà eléré orí ìtàgé, Idowu Philips ti gbogbo ènìyàn mọ si ìyá Rainbow ti ké gbajare lóri bí àwọn ènìyàn ṣe n fi orúkọ òun gbówó lọ́wọ́ àwọn enìyàn lórí àyélujara.

Mama Rainbow ni bó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣì ti ó ba àwọn ènìyàn mulẹ̀ ló fa ìdí abájọ ti àwọn ènìyàn fi n hu irú ìwà báyìí sùgbọ́n kìí ṣe ǹkan to dára láti ba orukọ elòmiran jk ki àyé ti wọ́n to dára.

"Tí ènìyàn yóò ba ṣe ǹkan, ẹ ṣeé ko dárá; kìí ṣe pé ki àwọn kan kàn jokò si ibikan ki wọ́n máà fi orúkọ Iya Rainbow gbowo lọ́wọ́ àwọn ènìyàn"

"Mí kìí ṣe 419, mí ò jalẹ̀ rí, mí kìí fi Olúwa wi gbowó lọ́wa ẹnìkankan oo, Ẹ dẹ jókòó sinú ilé ẹni Olúwa wí, Iya Rainbow ni kí ẹ gba báyìí, Iya Rainbow ni kí ẹ ṣe báyìí láti gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Mama Rainbow ní, ni bayìí okóbó àwọn ènìyàn wọ́nyi kò bímọ si tòsí mọ nítori wọ́n tí n ló ìrú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ lati lọ ba àwọn ènìyàn nlá nlá láti lọ gba owó.

Gbajúgbajà òṣèré náà ti wá kédé pé, òun kò rán ẹnikẹ́ni níṣẹ́ lati gbowo ni orúkọ òun.

Ó rọ gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti dẹkun àti máà fun ẹnikẹni lówó ni orúkọ oun tí òun tìkara òun ko ba ti yọju sí wọ́n àti pé ti òun bá nílò owó, òun ti mọ ibi ti òun yóò lọ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Abilekọ Philips ní òun kò ràn ẹníkẹ́ni níṣẹ́, àti pé gbájùẹ (419) ní wọ́n, o wá ni òun kò ní ṣepè fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ nítori pé ìyá aládura ni òun kò sì ta láti ṣépè.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil

Bákan náà ló rọ̀ wọ́n ki wọn ma ba orúkọ ti òun ti n tóju láti ààdọta ọdún sẹ́yìn jẹ́ nítori kò bàjẹ́ láti ìgbà ti òun ti ń lò bọ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa