Yoruba Films: Lizzy Anjorin yẹ́ iyabo Ojo sí kí ọjọ́ ìbí rẹ̀ tó pé

Awn oṣere Yollywood

Oríṣun àwòrán, OTHER

Bi awọn oṣere fiimu yoruba ṣe maa n ẹ ara wọn si tile tile bi wọn ba n ṣe ohun rere to fi mọ ọjọ ibi tiwọn ati ti mọlẹbi wọn maa n jẹ ohun iwuri to bẹẹ ti awọn ololufẹ wọn gan ko le ṣai da si ikini lori ayelujara.

Bi ko ba ti si gbọn mi si i, omi o to o laarin oṣere meji, iṣọwọ yẹra ẹni si laarin wọn maa wu ni jọjọ.

Iyabo Ojo ṣe ọjọ ibi ọdun mejilelogoji

Fun apẹrẹ, bi o til jẹ pe o fẹ sa pẹrẹ diẹ laarin gbajugbaja oṣere Lizzy Anjorin ati akẹgbẹ rẹ Iyabo Ojo lasiko ija to waye laarin Lizzy ati Toyin Abraham, ṣe ni idunu Lizzy anjorin pọ to debi pe ko wa si i lọkan pe oni ọj kọkanlelogun gangan ni ọjọ ibi Iyabo Ojo ṣugbn o ti ṣaaju gbogbo eniyan ki i ku ayẹyẹ ọjọ ibi ni ogunjọ osṣu kejila loju opo instagram rẹ.

Sibẹ sibẹ, eyi ṣi wu ni lori jọjọ tori o mu ki awọn akẹgbẹ wọn naa wa da ara wọn lọwẹkẹ eyi si mu inu awọn ololufẹ wọn dun lati ba wọn yọ.

Femi Adebayo Salami ro dẹdẹ ninu asọ oke fun ọjọ ibi ọmọ rẹ

Bakan naa ni awọn oṣere wọ si oju opo instagram ọmọ Ọga Bello naa, Femi Adebayo lati ki mọ rẹ to pe ọdun kan lonii ku ayẹyẹ ọjọ ibi.

Ọna ati gbe aṣa ilẹ wa larugẹ ti Femi Adebayo gbe yọ ninu imura tirẹ ati ọmọ ọlọjọ ibi ti wọn jọ fọ si agbada aṣo oke ibilẹ Yoruba jẹ ohun to wu awọn ololufẹ rẹ lori jọjọ́.

Lai tii mọ nipa Tiata, ọmọ Aremu Afolayan gba iyẹsi awọn oṣere

Eleyi maa ṣafihan ifẹ ati ibaṣepọ to gun to wa laarin awọn oṣere to fi le mu wọn nawọ ifẹ si idile ara wọn lasiko ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ tabi jọ ibi.

Eyi jẹyọ gẹgẹ bi awọn gbajugbaja oṣere ẹgbẹ Aremu Afolayan ṣe bọ soju opo rẹ lati yẹ ọmọ rẹ obinrin si toun naa n ṣe ọjọ ibi ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kejila.

Gbajugbaja ni Aremu Afolayan laarin awọn oṣere Yoruba toun gan si tun jẹ ọmọ agba oṣere kan funrarẹ, Adeyemi Afolayan bẹẹ o fẹrẹ jẹ gbogbo ọbakan rẹ ni oṣere.

Kunle Afolayan, Gabriel Afolayan ati Moji Afolayan.

Àkọlé fídíò,

'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'