Christmas: Kò sí ọdún tí ọjà ré tà tó ti Kérésì ọlọ́dọọdún- Alhaja Shakirat

Ọja Keresi kìí ṣe ọja ojoojumọ rara- Arabinrin Thomas.

Gbajugbaja olorin juju ni Naijiria, Ebenezer Fabiyi ti gbogbo eeyan mọ si Obey Commander ti kọ orin pe, ''ninu ọdun to m bẹ laye, ti keresi lo yatọ, to jẹ ọdun alarinrin...''

Nigba ti ikọ BBC jade lọ si ọja lọ wo awọn nkan to n ta warawara lasiko yii ni awọn ọlọja fidi orin yii mulẹ lori bi ọja wọn ṣe n ta lasiko yii.

Diẹ lara awọn ti BBC ba sọrọ ni Alhaja Shakirat Abimbola, Arabinrin Thomas, Iya Lekan, ati Iya Waris ti wọn menuba awọn ọja ọdun ati bi wọn ṣe n ta si lasiko ọdun keresi ti 2019 yii.

Awọn ontaja yii ṣalaye pe, tọmọde tagba lo maa n ra nkan ọdun keresi bii fila, ina ọdun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Fila ọdun Keresi, ina Ọlọrun, bata, aṣọ, gilaasi oju, aago ọwọ ọmọde, feere ati awọn nkan iṣere miran ni ọja ọdun ti kii ṣe ọja ojoojumọ.

Ìbí Jesu Kristi ni awọn onigbagbọ gba pe wọn n ranti ni asiko ọdun keresimesi.

Eyi maa n waye ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kejila, ni ọdọọdun ti ko yipada ri lati ẹgbẹlẹgbẹ ọdun ti wọn ti n sami ayẹyẹ ọjọ ibi Jesu naa.