Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà

Ọpọ awọn onibara ko ni fi owó asan silẹ ki Teelọ le rii lo lasiko- Aranṣọ amunidara

Bi ọdun keresimesi ti n kan ilẹkun bayii ni ọpọ awọn eeyan ti n sọrọ lori bi awọn aranṣọ ṣe n fun wọn ni ijakulẹ.

Wo awọn igbesẹ to yẹ ki o gbe lasiko ọdun ki o ma baa ni ijakulẹ lasiko ọdun Keresi ti 2019 Wò ìdí tí téélọ̀ rẹ fi já ọ kulẹ̀ lásìkò ọdún Kérésìmesì

Ki a maa baa gbọ ẹjọ ẹnikan da bii agba oṣika ni a ṣe kan si awọn amunidara ti wọn n ran aṣọ naa pe ki lo n ṣokunfa ijakulẹ fawọn onibara wọn?

Awọn amunidara naa mẹnuba igbesẹ to yẹ ki onibara to fẹ ranṣọ maa gbe.