Akurẹ Kidnap: Èmí kò ṣetán láti gbọ́ ẹ̀jọ yín lónìí, ó di 2020- Adájọ́ Adeyanju

Àkọlé fídíò,

Akurẹ Kidnap: Èmí kò ṣetán láti gbọ́ ẹ̀jọ yín lónìí, ó di 2020- Adájọ́ Adeyanju

Èmí kò ṣetán láti gbọ́ ẹ̀jọ yín lónìí, ó di 2020- Adájọ́

Laarọ oni, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila ni awọn olopaa ipinlẹ Ondo ko awọn eeyan yii lọ sile ẹjọ.

Wọn fẹsun kan awọn ara ilu naa pe awọn ni wọn ṣe iku pa ọlọpaa kan ti o gbẹmi mi lasiko ti wọn dana sun ile ijọsin Wolii So titobi rẹ.

Adajọ Charity Adeyanju lo wa sọ pe ki wọn da awọn ti wọn ko wa siwaju oun pada si ahamọ titi di ọjọ kẹta, oṣu kinni, ọdun 2020.

Àkọlé fídíò,

'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

Lara ẹsun ti wọn fi kan awọn ara ìlú ti ọwọ tẹ naa ni pe wọn ji awọn ohun ini wolii So titibi rẹ to n jẹ ẹjọ lori ọmọkunrin Gold Kolawole to dawati nile ijósin rẹ bayii.

Wọn ni awọn eni naa ko nkan bii amohunmaworan, ohun eelo igbohunjade, awọn ẹya ara ọkọ ti wọn ko jona tan ati awọn nkan miran nile ijọsin Miracle Center.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: Àwọn abiyamọ fẹ̀hónúhàn lórí ọmọ tí wan jígbé nílé ìjọsìn Akurẹ

Agbejoro àwọn ọ̀daràn náà, John Saliu ṣàlàyé pé, ọlọ́pàá kò ní aridaju tí ó péye pé àwọn onibara oun ni wọn jó ilé ìjọsìn náà àti wí pé, kii ṣe àwọn ni wọn pá ọlọ́pàá tí ó kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà

Nínu èsì tìrẹ, alukoro àjọ ọlọ́pàá ni Ipinle Ondo, Femi Joseph ṣàlàyé pé, gbogbo àwọn mẹ́tàlá tí adé ọ̀rọ̀ náà sì mọ lórí ni wọn yóò jìyà tó tọ́ àti èyí tí ó yẹ leyin igbẹjọ.

Àkọlé àwòrán,

Èmí kò ṣetán láti gbọ́ ẹ̀jọ yín lónìí, ó di 2020- Adájọ́ Adeyanju

O ni igbẹjọ ni ajọ ọlọpaa n duro de ni kete ti igbejo bá bẹ̀rẹ̀ ni péréwu ni ọjọ́ kẹta, oṣù Kínní ọdún 2020.

Ẹ̀sùn olè, ipaniyan àti iba dúkìá jẹ́ ní wọn fi kàn wọ́n, to fi mọ igbabode fawọn agbofinro ni wọn tun ni wọn ṣe si.

Sugbon báyìí, ilé ẹjọ́ ni kí gbogbo àwọn mẹ́tàlá náà lọ roọkun sì ọgbà ẹ̀wọ̀n Olokuta ni ipinlẹ Ondodi ìgbà tí igbejo wọn yóò bere ni ọjọ́ kẹta oṣù, Kínní ọdún tó ń bọ̀.