Sowore ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ló gba òun lọ́wọ́ àhámọ́ DSS

Àkọlé fídíò,

Sowore ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ló gba òun lọ́wọ́ àhámọ́ DSS

Ajafẹtọ ọmọniyan ni, Ọmọyẹle Ṣoworẹ to gba itusilẹ rẹ ninu ahamọ ajọ DSS ni ọjọ iṣẹgun ti ṣalaye wi pe awọn ọmọ Naijiria lo mu ki itusilẹ oun kuro ninu ahamọ wa si imuṣẹ.

Sowore sọ ọrọ yii nigba to n ba awọn akọroyin atawọn ololufẹ rẹ to duro dee nigba ti o n kuro ni ileeṣẹ ajọ DSS nilu Abuja.

Soworẹ to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ pupa kan ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ di mọ pẹlu idunnu pẹlu ariwo 'Revolution now" bi wọn ṣe n di mọ ọ.

Oríṣun àwòrán, NewsCentralTV Sumner Shagari Sambo

Mo dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria. Awọn ọmọ Naijiria lo mu ki o ṣeeṣe.

Ko si ẹnikẹni to lee mu awọn eniyan to ba ti ṣetan ni agọ. Mo ki Ọmọ orilẹede Naijiria ku ọdun keresi.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Ajọ DSS tu Soworẹ silẹ ni ibamu pẹlu aṣẹ agbẹjọro agba fun orilẹede Naijiria to tun jẹ Minisita feto idajọ, Abubakar Malami.

Oríṣun àwòrán, Sahara reporters

Ni ọsẹ meji sẹyin ni awọn agbofinro DSS fi tipatikuuku mu Soworẹ ni ile ẹjọ lẹyin ti adajọ ile ẹjọ giga kan ni ilu Abuja ti ni ki wọn tu u silẹ.

Ìjọba àpapọ̀ ti paṣẹ pé kí wọ́n tú olubadamọraǹ lóri ètò ààbò Sambo Dasuki ati agbẹtẹru RevolutionNow Omoyele Sowore silẹ̀ nínú àhámọ.

Minisit fuún ìdájọ àti agbẹjọro ijọba apapọ Abubakar Malami ló kéde ọ̀rọ̀ náà nínú àtẹjáde kan lọ́sàn ònà (ọjọ iṣẹ́gun).

Malami ní ijọba gbé ìgbésẹ̀ náà nítori ìdájọ tí ilé ẹjọ dá àwọn mejeji.

Àkọlé fídíò,

Akurẹ Kidnap: Èmí kò ṣetán láti gbọ́ ẹ̀jọ yín lónìí, ó di 2020- Adájọ́ Adeyanju

Malami rọ àwọn mejeeji lati dúro ti àwọn ǹkan ti o rọ mọ gbigba oniduro wọ́n, ki wọ́n sì dẹ́kun láti hu ìwà yóò da omi alafia ilú rú àti ètò àbo ilú, tabi lati lodi si ìgbẹ́jọ wọ́n nile ejọ.

Malami ni ìgbẹ́sẹ̀ náà kò sèyin ẹka ofin ọdun 1999 nipé àwọn nilati fun Sambo Dasuki ni ominira gẹ́gẹ́ bi idájọ ilé ẹjọ kotẹmilọrun ati oniduro Sowore ti ile ẹjọ gba.

O ni: "mo ti pasẹ fun àwọn àjo ọtẹlẹmuyẹ ki wọ́n tèlé àṣẹ ilé ẹjọ to tu Sowore silẹ.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun