Christmas & food price: Bí adìyẹ, ìrẹsì ṣe dí góòlù fún àsìkò ọdún

Christmas & food price: Bí adìyẹ, ìrẹsì ṣe dí góòlù fún àsìkò ọdún

Okuta ti pọ̀jù nínú ìrẹsì tí àwọn àgbẹ̀ Naijiria ń ṣe- Alásè

Gẹgẹ bi ọdun keresimesi ṣe ń kogba lọ ti ayẹyẹ ọdun tuntun n wọle de wẹrẹ, irẹsi ni ounjẹ gboogi ti ọpọ maa n se fun ọdun.

Bi awọn kan ba ṣe n din ọbẹ ata sii naa ni awọn miran maa n yii pọ mọ ata ni jọlọfu ti awọn miran maa n din in pẹlu ororo ati ata dudu pẹlu eroja mii.

Awọn ọlọja ati alase sọrọ ni kikun ipa ti ẹnu bode ti a ti pa yii n ko lori ọwọn gogo ounjẹ bii irẹsi ati ororo.

Wọn gba ijọba ni imọran lati ran awọn agbẹ lọwọ ki wọn le maa pese irẹsi to dara ti ko ni okuta biii ti ilẹ okeere.

Arabinrin Opaleye, Adepeju Ruth Dagunduro àti awọn miran sọrọ lori bi ọwọn gogo ounjé bii irẹsi atio ororo ṣe han ninu ina dida fun keresi ọdun 2019