Christmas robbery: Olè yabo báńkì,fọ́n owó ká fáwọn èrò lẹ́yìn tó pariwo'Merry Christmas'

colorado
Àkọlé àwòrán,

Olè yabo báńkì. fọ́n owó ká fáwọn èrò lẹ́yìn tó pariwo'Merry Christmas'

Arakunrin oyinbo onirugbọn kan lo deede yabo ile ifowopamọsi kan ni Colorado Springs ni orilẹ-ede America.

Kete to wọle lo jẹ ki awọn oṣiṣẹ banki naa mọ pe ole ni oun ati pe ki awọn onibara ma bẹru.

Lẹsẹkẹsẹ naa ni awọn oṣiṣẹ banki ko wulẹ janpata mọ nitori ẹmi wọn ti arakunrin naa si raaye ko owo to pọ bo ṣe wuu.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Awọn oju mi to ti iṣẹlẹ yii ṣoju wọn ni bo ṣe ko owo tan lo rin jade sita banki naa to si bẹrẹ si ni fọn owo naa ka.

Wọn ni bo ṣe n fọn owo naa fawọn ero to n kọja lọ nita banki lo n pariwo " Merry Christmas"

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Awọn agbofinro ṣalaye pe ọkunrin agbalagba naa jale owo yii ni Academy Bank to wa ni Colorado Springs lasiko ounjẹ ọsan ni.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Dion Pascale, ọkan lara awọn ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun akọroyin 11 News to wa ni Colorado pe iyalẹnu nla lo jẹ fun gbogbo ero oju popo bi ọkunrin naa ṣe n ko owo jade lati inu baagi owo to si n fón won da sita.

Iroyin ni kete ti arakunrin yi fọn owo naa ka tan lo wọ inu Starbucks ti wọn ti n ta awọn ohun mimu tutu bii tíì ati kọfi lọ.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Ẹni ti ọdun ba ti bá láyé yẹ kó dúpẹ́

Awọn o ṣoju mi ni bo ṣe wọ inu starbucks tan lo jokoo to n reti awọn ọlọpaa pe wọn a to wa mu oun.

Iroyin ni awọn ero oju titi fi ara balẹ ṣa owo naa ti onikaluku ko si kaa si ẹbun ọdun keresi ṣugbọn ti wọn daa pada sinu ile ifowopamọsi naa ti ọkunrin ọhu ti koo bọ sita tẹlẹ.

Awọn agbofinro Colorado Springs pe orukọ okunrin naa ni David Wayne Oliver.

wọn ni ọmọ ọdun marundinlaadọrin ni ati pe ko dabi ẹni pe o ni oluranlọwọ kankan ti wọn jọ jale naa rara.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà