Christmas: Ẹ ronúpìwàdà lásíkò ọdún, àti àwọn ìkíni mìrán tó jẹ yọ fún Kérésì

awọn alasẹ
Àkọlé àwòrán,

A ku ọdun Keresi ni koowa n kira wn lonii

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ki awọn ọmọlẹyin Kristi to wa ni orilẹ-ede Naijiria ku oriire ọdun Keresimesi.

Ninu ikini naa, Buhari sọ pe ki gbogbo ọmọ Naijiria fi awọn nkan rere ti ọdun Keresimesi duro fun han ninu iwa wọn.

Buhari lo anfaani naa lati kesi gbogbo awọn ti iṣẹ ọwọ wọn ko mọ, paapaa awọn ole, ajinigbe, janduku, agbesunmọmi, ati awọn to tako ọrọ aje Naijiria lati ronupiwada.

O ni ki wọn o si darapọ mọ awọn to ni erongba lati tun Naijiria ṣe.

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Buhari ni ti awọn oniwakiwa ko ba jawọ, wọn yoo gba ko ẹsan iwa wọn, nitori pe awọn oṣiṣẹ alaabo ti ṣetan lati gbogun ti wọn, ti wọn yoo si ṣẹgun wọn.

Bakan naa ni Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar naa parọwa ifẹ fun gbogbo Kristiẹni pe ifẹ lakoja ofin

Atiku gbadura ọjọ iwaju rere pẹlu ireti fun awọn ọmọ Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun

Omowe Goodluck Ebele Jonathan to ti tukọ Naijiria sẹyin ninu ikinni ọdun keresi ti é ṣalaye nipa ibi Jesu ati ohun to duro fun.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Gomina Seyi Makinde to n ṣe ọjọ ibi pẹlu ìbí Jesu olugbala naa sọrọ akin ati ironupiwada bi a ṣe sami ayẹyẹ Keresi ọdun yii pe:

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi naa ti ki awọn eniyan ipinlẹ rẹ ku oriire ọdun Keresi.

Ninu iṣẹ ikini ọdun to ran si wọn, Fayemi rọ wọn lati maa gbe igbeaye wọn ninu ifẹ, ififunni ati alaafia, to ṣe e farawe.

Fayemi to fi ikede naa sita lati ọwọ Akọwe ikede Agba fun un, Yinka Oyebode, O rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ifẹ ba ara wọn gbe lai fi ti ẹ̀sìn ṣe.

O ni ki wọn o si tun maa gbadura fun iṣọkan ati ilọsiwaju Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Ẹni ti ọdun ba ti bá láyé yẹ kó dúpẹ́

Oludije sipo igbakeji aarẹ lẹgbẹ PDP, Senetọ Peter Obi pe fun ajọdun keresi to ni ironupiwada.

O ni ki awọn ọmọlẹyin Kristi fi asiko yii ṣe iranti iṣẹ igbala ti Jesu Kristi ṣe lataari bibi ti a bii sinu ibujẹ ẹran yii.