Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlọ́pàá nítorí Múrí márùn ún- Adebayo Olaide

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlọ́pàá nítorí Múrí márùn ún- Adebayo Olaide

Ọjọ maleegbagbe ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹfa, ọdun 2009 jẹ fun mi- Adebayo

Adebayo Olaide ti awọn agbofinro sọ di alaabọ ara ọsan gangan loju ọna Ogbomọṣo si abule Alagbayun ni BBC Yoruba ba lalejo lati mọ nkan to n ṣẹlẹ gangan ni pato.

O ṣalaye bi wọn se da oun duro lọna ti wọn gba ọgọrun un naira lọwọ oun ti awọn ko si ja fun idi kankan.

O ni iyalẹnu lo jẹ bi ọkan ninu wọn ṣe deede fidi ibọn fọ oun loju ti wọn si salọ lai gbe oun lọ sile iwosan.

Lẹyin o rẹyin gbogbo igbẹjọ iṣẹlẹ yii nile ẹjọ, Agbejọro Peter Idowu to ṣoju Adebayo ninu igbẹjọ naa ba BBC sọrọ.

O fidiẹ mulẹ pe Adajọ ni ki ileeṣẹ ọlọpaa san ogun miliọnu naira fun Adabayo gẹgẹ bii owo itanran.

O ni titi di akoko yii, ojoojumọ nile isẹ ọlọpaa n ni faili igbẹjọ Adebayọ ti sọnu ni ọọfiisi wọn ti awọn si n mu omiran lọ.

Ariwo ẹ dakun, ẹ ma jẹ ki iya yii jẹ mi gbe ni Adebayọ n pa lasiko yii fun gbogbo agbaye pe ki wọn dide iranlọwọ ki ileeṣẹ ọlọpaa le ṣe ohun to yẹ fun oun.

Gbogbo igbiyanju ileeṣẹ BBC lati gbọ iha ti awọn agbofinro ti ọrọ kan yanju ja si pabo.

Àkọlé àwòrán,

Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide

Titi di asiko yii, ileeṣe ọlọpaa ko tii sọ nipa igbesẹ ti wọn n gbe lati san ogun miliọnu ti Adajọ sọ.