Christmas: Bi àwọn kan ṣé n jẹ àsun ní àwọn míì n ṣeré lórí omí láti gbádùn Kérésì àná

Ẹni ọdun ba ti ba laye di dandan kó ṣe ọpẹ nitori pé ẹni to wa láye kò sàn jú àwọn to ti lọ.

asun
Àkọlé àwòrán,

Asun to dùn kọja bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti BBC kan fi ṣagbeji ara ni ana lati fi jẹ igbadun ọdun Keresi to yatọ!

Àkọlé àwòrán,

Awọn ẹbi kan ree ni inu omi okun Elegushi ni ipinlẹ Eko ti wọn n gbadun aye wọn fun Keresimesi ti ọdun 2019.

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ ẹbi ati ara ni wọn gbagbe ọrọ ana ti wọn korapọ jọ n ba ara wọn ṣere pe ẹ̀mí ri ẹ̀mí ni Keresi ọdun 2019

Àkọlé àwòrán,

O n gbona fẹẹli- Pọfu pọọfu aladun ni awọn kan n ta ni Ẹlẹgushi ni ipinlẹ Eko fawọn to wa gbadun Keresi leti okun lanaa.

Àkọlé àwòrán,

Ọdun Keresimesi yatọ ninu gbogbo ọdun to wa laye ni eyi ti ami awọ pupa ati awọ ewe maa n saaba han ninu aṣọ, fila tabi jingi oju ti awọn eeyan maa n wọ

Àkọlé àwòrán,

Ṣẹ ẹyin naa ti gun ẹṣin ni kẹ́sẹ́ ri lori iyanrin okun bii ti awọn arabinrin ti wọn n jaye ori wọn lori ẹranko oju ogun yii?

Àkọlé àwòrán,

Ẹlẹsẹ ayo to ba to gbangba sun lọyẹ ko darapọ mọ awọn ọkunrin to n fi ere bọọlu lori omi yii pa ironu rẹ ti wọn n ṣere ọdun bayii

Àkọlé àwòrán,

Ẹ jẹ ki a gbagbe ohun ti ọwọ wa ko tẹ lọdun 2019 ki a fi ayọ ati imoore han si Ọba Oke to da wa si nitori pe ọdun 2020 maa dun pupọ