Kunle Afod: Òṣèrébìnrin tí wọ́n bá fi ìbálòpọ̀ lọ̀ 'torí ìṣẹ́, kó bọ́ síta láti sọ̀rọ̀ -

Afod

Oríṣun àwòrán, KunleAfod/Imstagram

Àkọlé àwòrán,

Òṣèrébìnrin tí wọ́n bá fi ìbálòpọ̀ lọ̀ 'torí ìṣẹ́, kó bọ́ síta láti sọ̀rọ̀ - Kunle Afod

Gbajumọ oṣere, Kunle Afod ba BBC Yoruba lalejo, o ṣi dahun ọpọlọpọ ibeere nipa igbe aye rẹ gẹgẹ bi oṣere lati igba to ti bẹrẹ.

Lori orukọ rẹ, ti ọpọ ti maa n wadii ohun to tumọ si, nitori pe kii ṣe orukọ to wọpọ nilẹ Yoruba, Kunle Afod sọ pe: "Orukọ mi, Afod kii ṣe inagijẹ" .

Gbigbọnju ti mo ba baba mi, Rẹmi Afod ni wọn n jẹ.

Ohun ni emi naa ṣe n jẹ Adekunle Afod. "Orukọ ti wọn n jẹ ni ilu Ibadan ni orukọ mi," "ọmọ Ibadan ni mi". "Orukọ Yoruba ni orukọ mi."

Àkọlé fídíò,

Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

"Awọn pupọ ninu mọlẹbi wa n jẹ Afọdunrinmi,"ṣugbọn mo fẹran orukọ naa bi baba mi ṣe n jẹ ẹ l'emi naa ṣe gba a bẹẹ.

Adekunle ni oun paapa ko mọ idi ti baba oun fi n jẹ orukọ naa.

O si fi awada sọ pe: "Ẹyin ti ẹ ba fẹ ẹ mọ, ẹ jẹ ki a lọ si ibi saare baba wọn, ta a ba kan ilẹkun, boya wọn maa da wa lohun.

Gẹgẹ bi Afod ṣe sọ, o ni ọdun 1973 ni wọn bi oun. Iyawo kan pere ni oun ni, o si bi ọmọkunrin mẹẹrin fun oun.

Àkọlé fídíò,

'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

"Mo ti ni ọmọ obinrin kan tẹlẹ."

Ti ẹ ko ba jẹ osere, iṣẹ wo lẹ ba ṣe? Awọn oloútú orin, (music producer) ni mi o ba tun ṣe.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Mo fẹran orin, ṣugbọn boya ohun mi ko dara to.

Emi ni mo maa n kọ ọrọ awọn orin ere mi, ki n to o gbe fun aburo mi Amin mi to n kọrin lati kọ ọ.

Lori awọn oṣerebinrin to maa n sọ pe awọn ọkunrin awọn maa n fi ilọkulọ lọ awọn, Afod sọ pe pupọ ninu nkan ti wọn n sọ nipa awọn osere ọkunrin jẹirọ ni.

O ni: "Lati ile ni ẹlomii ninu wọn ti ni lọkan pe nkan ti awọn fẹ ẹ lọ ṣe niyẹn.

Nitori pe ẹlomii ko fẹ rá, tabi rin ko to o de oke. Wọn ko fẹ ẹ kọṣẹ, wọn a maa bi yin pe ba wo lẹ ṣe maa ba awọn ṣe tawọn maa fi de oke ni kete ti wọn ba ti bẹrẹ iṣẹ ere."

"Oṣerebinrin to ba foju wina iru nkan bẹẹ, gbọdọ sọ sita lati ran awọn miran lọwọ. Kiiṣe nkan to dara rara ti eyi ba n ṣẹlẹ nitootọ."

Àkọlé fídíò,

Mo n wa'yawo - Falz

Lori irinajo rẹ ninu iṣẹ tiata, Afod sọ pe "oun ko mọ pe oun le laluyọ nigba ti oun bẹrẹ iṣẹ. Nitori pe awọn to ti dide bi i Aluwẹ, Ọga Bello la ba lẹnu iṣẹ."

"Mo ṣiṣẹ fun Wole Soyinka ati Bola Ige ri ninu ere ori itage.

Lẹyin naa ni mo darapọ mọ Adebayo Salami lori awada kẹrikẹri fun bi ọdun meje. Ki n tun to ba Yọmi Ogunmọla ati Antar Laniyan ṣiṣẹ."

Lori iwọkuwọ ati awọn aṣa ti ko fi bẹ ẹ bojumu ninu sinima Yoruba lode oni, Afod sọ wi pe ọwọ ajọ ti ijọba gbe kalẹ lati maa yẹ sinima wo, Censors Board lo yẹ ko mojuto ojulowo sinima.

"Ti wọn ba wọgile sinima kan nitori pe ko dara to, olukuluku yoo mu iṣẹ naa ni òkunkundun.

Àkọlé fídíò,

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide

Kunle ni: Ẹnu ẹgbẹ ko le ka ẹnikẹni tabi sọ pe sinima kan ko dara. Ọwọ ijọba lo wa."

Afod tẹsiwaju lati sọ pe ere mẹta lo gbe oun jade; Owo Blow, Solo Makinde, ati Pata pupa. "Mẹtẹẹta jade pọ lẹkan naa ni okiki mi ṣe burẹkẹ lọdun naa. Ọdun to tẹle ni mo ṣe Ija ọmọde."

"Ipenija owo ni mo le sọ pe mo ni lẹnu iṣẹ. Gbogbo iyoku, iriri ni mo ka wọn si. Mo ti ni ijamba ọkọ ri lẹnu iṣẹ nigba ti mo fi wa ni ọdọ Ọga Bello."

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ