Sotitobire Church: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Sotitobire Church: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Ohun to pamọ, oju Olorun lo too ni ọrọ Kolawole Gold to dawati di bayii.

Oriṣiiriṣii iṣẹlẹ lo ti ṣẹlẹ sẹyin nipa Kolawọle Gold, ọmọde to dawati ninu ijọ Sọ titobi rẹ ti Wolii Babatunde Samuel Alfaa ni tukọ rẹ nilu Akurẹ.

Kayeefi BBC Yoruba fun ipari ọdun 2019 yanana ootọ ati irọ to wa ninu gbogbo awọn ohun to ti ṣẹlẹ ni Akurẹ lati ọjọ ti ọmọ yii ti sọnu.

Bi a ṣe gbọ ọrọ lẹnu Wolii Alfaa ti ọrọ kan gan an, la ba arabinrin Modupẹ to jẹ iya ọmọ ati ọgbẹni Temitọpẹ to jẹ baba ọmọ sọrọ.

Koda, a kan si agbejọro Wolii So titobi rẹ, Alukoro awọn agbofnro, Femi Joseph, ẹbi ọmọ to sọnu ati gbogbo awọn ti iṣẹlẹ yii kan.

Oluwa lo mọ ẹjọ da ni ọrọ ku si ṣugbọn ireti ati igbagbọ koowa ni pe Olọrun a ṣe Gold Kolawọle to dawati ni riri fun gbogbo aye.