Kazakhstan: Ó kéré tán, ènìyàn mẹ́rìnlá tí kú nínú àjálù ọkọ̀ òfurufú tó já

ọkọ ofurufu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ó kéré tán, ènìyàn mẹ́rìnlá tí kú nínú àjálù ọkọ̀ òfurufú tó já

Ọkọ ofurufu Bek Air lo ja ni eyi ti o kere tan eniyan mẹrinla ti gbẹmi mi.

Ọkọ ofurufu yii ko eniyan mejidinlọgọrun ko to lọ forisọ ile kan nigba ti o jabọ.

Awọn alaṣẹ ni papakọ ofurufu ni ko pe ti ọkọ ofurufu yii gbera to fi jabọ kọlu ile kan ni aarọ ọjọ Ẹti to gbera.

Wọn ti ko awọn eniyan to to ọgọta ti wọn farap lọ sile iwosan bayii.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Z92100 ni nọmba ọkọ ofurufu naa to n ko ero lọ si Nur-Sultan to jẹ olu ilu Kazakhstan lati Almaty to jẹ ilu to tobi ju nibẹ.

Awọn eniyan to wa nitosi ibẹ ni ikuuku lo ṣu loju ofurufu nitosi ibẹ ṣugbọn wọn ko tii fidi ohun to fa ijamba naa mulẹ di asiko yii.

Àkọlé fídíò,

Mo n wa'yawo - Falz

Awọn alaṣẹ ni oṣiṣẹ marun un lo wa nibẹ ti wọn ni nkan bii aago meje kọja iṣẹju mejilelogun ni Almaty ni ọkọ naa jabọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ijọba Kazakhstan to n risi iṣẹlẹ abẹle ṣalaye pe ọmọ méfa lo wa ninu awọn to jalaisi nibi iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni ijọba ni wọn maa ṣagbekalẹ igbimọ to maa ṣe iwadii nkan to ṣẹlẹ gangan.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Aarẹ Qasym-Jomart Toqayev ti ranṣẹ ibanikẹdun sawọn ẹbi to padanu pẹlu ileri lati fiya to tọ jẹ ẹni ti ade ọrọ naa ba ṣi mọ lori.

Ọkọ ofurufu kan ti ja ri ni ọjọ kokandinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2019 to gbera ni ariwa Kokshetau ni Almaty nibi ti ogun eniyan ti doloogbe.

Oṣu kan ṣaju eyi ni baalu ologun to ran awọn eniyan mẹtadinlọgbọn lọ si ọrun aremabọ naa ṣẹlẹ ni guusu orilẹ ede ọhun.

Àkọlé fídíò,

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide