Nigeria Stowaway: Baalu tó ń lọ Owerri ni Ọdọmọkunrin náà fẹ́ gán- Airpeace

Balùú
Àkọlé àwòrán,

Agbófinro mú ọkùnrin to n gun baalu to fẹ́ gbera

Ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ silẹ̀ lónìí ní pápákọ̀ òfurufu ilú Eko nígbà tí ọkùnrin kan ti wọ́n ò tii dárukọ sárẹ gun bààlú Air Peace to n gbéra.

Awọn elétò ààbò to wà nibẹ̀ ni awakọ ofurufu aladani kan to ń bọ lẹ́yìn lo sáré ké gbajari ki wọ́n tó mú ọkùnrin náà.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ pápákọ ofurufu náà ko le fi ìdí ti ọkunrin òhun ṣe gbe irú igbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kété ti ọ̀rọ̀ naáà ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n ọwọ́ ti tẹ̀ẹ́.

Àkọlé fídíò,

'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Ẹ̀wẹ̀, ilé iṣẹ́ Airpeace ni ọkùnrin náà jẹ́ ọkàn lára àwọn ti wọ́n máa ń tèlé ọkọ ofurufu sálọ si ilẹ̀ òkèrè.

Ilé iṣẹ́ náà ni àfurasi náà ti wà ni àhámọ àwọn bàyìí fun ìfọrọ̀wánilẹnuwò.

Bayii ni àtẹjáde Airpeace ṣe lọ "Ní òwúrọ òni, ní dédé ààgo mẹsàn kọja iṣẹ́jú mẹwaà ni MMA1 nílù Eko ni bàà'lú Airpeace to n lọ Owerri n gbìyànju láti gbéra nigbati ọkunrin kan ti ko ti to ọmọ ogun ọdun bẹ jáde lati inu igbó lójú ọ̀nà ti bààlu yòó gbà láti sá tèlé bàálú náà."