Idí ti a ko ṣe tú El-Zakzeky silẹ láhàmọ́- Malami

El-Zakzeky
Àkọlé àwòrán,

Idí ti a ko tú El-Zakzeky silẹ láhàmọ́- Malami

Ìbèère ti gbode kan lẹ́yìn ti ìjọba orillẹ̀-èdè Naijiria ni ki wọ́n dá Olubadamora lori ọ̀rọ̀ abo tẹ́lẹri Sambo Dasuki àti ajijagbara #RevolutionNow Omoyele Sowore pé, èèṣe ti wọ́n ko fi da El-Zakzeky náà silẹ̀ lálàfíà.

Agbẹjoro àgbà lorilẹ̀-èdè Naijiria ti sàlàyé ìdí ti wọ́n ko fi da El-Zakzeky àti aya rẹ̀ Zeenat silẹ bi wọ́n ṣe dá àwọn méji tokù silẹ̀ láipé yìí.

Malami ni àwọn ko tu wọ́n silẹ̀ nitori pé ìpínlẹ̀ wọ́n lo n bá wọ́n ni ẹ̀jọ, kìí ṣe ìjọba apapọ.

O sọ ninu àtẹjáde kan ti agbẹnuso rẹ̀ Umar Gwandu fọ́wọ́si pé, ìjọba apapọ kìí dá si ọ̀rọ̀ ti kò ba kan an.

Malami sọ pé ọwọ ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ni ìgbéjọ El-Zakzeky àti ìyàwó rẹ̀ wà, nítori náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò le dà bi ti Dasuki àti Sowore.

O fi kún pé, ẹsùn ìpàniyan ni wan fi kan El-Zakzeky àti iyawo rẹ̀, eyí lo jẹ ko nira fun ijoba ipinlẹ Kaduna lati jọ̀wọ́ wọ́n silẹ̀

Agbẹjoro àgbà naa fi kún pé, fifi Dasuki àti Sowore silẹ gàn kan jẹ́ ìwoniṣe láànu ni láti ọ̀dọ̀ ìjọba apapọ

Itúsílẹ̀ Sowore àti Dasuki wáye lẹ́yìn ọdún mẹ́rin ti Dasuki ti wà láhàmọ ti ilé ẹjo si ti paṣẹ itúsílẹ̀ rẹ̀ bi ìgbà márùn ní ilé ẹjọ ọtọọtọ.

Bẹẹ naa ni ile ẹjọ ti paṣe itusilẹ Sowore nígbà meji ọtọtọ loṣu kẹsan an ati oṣu kọkanla ọdun yii, ki wọn to tu silẹ.

Malami tẹ̀pẹ̀lẹ mọ pé kìí ṣe nitori ǹkan ti àwọn ilẹ̀ òkèrè ń sọ ló jẹ́ ki àwọn ti Sowore silẹ bíko ṣe ìfàraji ìjọba láti bọ̀wọ̀ fún òfin.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá