Islamic State' ní Nàìjíríà bẹ́ àwọn Kristiẹni lórí ní ìpínlẹ̀ Bornu

Aare Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Eto aabo to peye ti jẹ ipenija nla fun orilẹede Naijiria

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti rọ awọn ọm Naijria pe ki wọn ma ṣe jẹ ki awọn agbesunmọmi pin orilẹede niya lọna ti ẹsin.

Eyi waye lẹyin ti ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State West Africa Province (ISWAP) ṣekupa awọn Kristẹni atawọn Musulumi kan ni ilu Borno gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ ọ.

"A o gbudọ gba ki awọn agbesinmọmi pin wa niya nipa kikọ ẹyin awọn Kristẹni si ti awọn Musulumi nitori awọn apaniyan yii kii ṣe aṣoju ẹsin Islam rara". eyi ni aarẹ Buhari sọ.

Ẹgbẹ agbesumọmi Islamic State IS, fi fọran kan lede, nibi ti wọn ti pa awọn Kristẹni mọkanla lorilẹ-ede Naijiria.

Wọn ni awọn pa awọn eeyan naa lati gbẹsan bi orilẹ-ede Amẹrika ṣe pa olori wọn, Abu Bakr al-Baghdadi ni Syria loṣu kẹwaa ọdun yii.

Awọn eeyan naa ti gbogbo wọn jẹ okunrin ni wọn ji gbe ni ipinlẹ Bornu.

Oríṣun àwòrán, @A_Salkida

Àkọlé àwòrán,

Wọn yibọn pa ọkan lara awọn eeyan ọhun, lẹyin naa ni wọn bẹ awọn mẹwaa to ku lori

Aarẹ ni aabo gbogbo ọmọ Naijiria jẹ ojuṣe oun bẹẹ si ni iku alaiṣẹ Kristẹni tabi Musulumi maa n ba oun lọkan jẹ.

O tẹnu mọ pe awọn agbesunmọmi yii ko ni aato kankan to mọyan lori ayafi iṣẹ ibi ṣiṣe nipa ki wọn kan maa pa awọn alaiṣẹ lodi si itọni ẹsin Islam eyi to lodi si ipaniyan.

"Ko si musulumi ododo kankan ti yo maa ke 'Allahu Akbar' ti yoo si maa pa awọn alaiṣẹ tabi ṣe ibi eyi ti Qur'an lodi si".

Aarẹ Buhari wa pe gbogbo ọmọ Naijiria lati wa ni isọkan lodi si awọn agbesunmọmi yii ki wọn ma si faaye gba awọn ọrọ to le ran ẹgb agbesunmọmi Boko Haram ati ISWAP lọwọ.

Ọjọ keji ọdun Keresi ni IS gbe fidio naa jade, leyi to mu awọn onwoye ohun to n lọ sọ pe wọn fẹ mọọmọ jẹ ko ṣe dede ọdun Keresimesi ni.

Ijọba Naijira ko tii sọ ohunkohun lori fọran ọhun, bẹẹ naa ni ẹgbẹ Islamic State ti Iwọ oorun Afrika ko ti sọrọ kankan nipa rẹ.

Lara awọn ohun to wa ninui fidio naa ni bi wọn ṣe yibọn pa ọkan lara awọn eeyan ọhun, ti wọn si bẹ awọn mẹwaa to ku lori.

Lẹyin naa ni wọn sọ pe "A pa awọn eeyan wọnyi lati gbẹsan iku awọn ọga wa, ti Abu Bakr al-Baghdadi wa lara wọn.

Ẹgbẹ Boko Haram jẹ ọkan lara awọn agbesumọmi to n doju ija kọ awọn ọmọ ogun Naijria.

Ṣugbọn ni ọdun 2016 ni awọn kan lara wọn yapa, ti wọn si darapọ asia ẹgbẹ Islamic State ti agbegbe iwọ oorun Afrika.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá