Somalia: Ìbúgbàmù nínú ọkọ̀ tí f'ẹ̀mí èèyàn 76 ṣ'òfò

Ikọlu Somalia

Ṣe ni onka iye awọn to ba iṣẹlẹ naa rin n goke sii tori naa, a ko tii le sọ pato iye awọn to fara gba.

Ṣugbọn lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, o kere tan, o ti di eniyan mẹrindinlọgọrin ti iroyin sọ pe ibugbamu ọkọ pa ni olu ilu orilẹede Somalia.

Lọsan ana, Dokita Mohamed Yusuf to jẹ oludari ile iwosan Madina sọ fun ile iṣẹ iroyin AP pe awọn ti gba oku eniyan mẹtalelaadọrin o ti wa le sii bayii.

Ni bayii ko tii si ẹgbẹ agbesunmọmi kankan to sọ pe awọn lawọn wa nidi iṣẹlẹ naa ṣugbọn lọpọ igba ni ẹgbẹ al-Shabab ti ṣe ikọlu sibẹ.

"Ki Allah ṣaanu fun awọn to fara gba ninu iṣẹlẹ laabi yii", minisita tẹlẹ fun aabo abẹlẹ sọ eyi.

Ṣaaju nibẹrẹ oṣu yii ni wn pa eeyab marun un nigba ti gbẹ al-Shabab kọ lu ile igbaf kan ni Mogadishu ti awọn gbajugbaja oloṣelu, awọn sanmọri atawọn ologun maa n na.

Àkọlé fídíò,

Orí yọ èèyàn mẹ́ta nínú ilé tí ọkọ̀ bàálù dédé já wọ̀