Abuja Bank Robbery: Agara dá ìgárá ọlọ́sà, ọwọ́ sìnkùn ọba tẹ̀ ẹ́

Adigunjale

Oríṣun àwòrán, Buharist Reporter/Facebook

Lọwọlọwọ, ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn adigunjale to ṣe ikọlu si ile ifowopamọ to wa lagbegbe Mpape ni ilu Abuja.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa olu ilu orilẹede yii, ASP Mariam Yusuf j ko di mimọ fun awọn oniroyin pe ohun gbogbo ti pada bọ sipo lagbegbe naa ti ọwọ awọn si ti tẹ mẹrin lara awọn afurasi adigunjale naa.

Iroyin ti a gbọ sọ pe awọn ọlọpaa ti yinbọn pa ọkan lara wọn.

Ọkan lara awọn adigunjale

Oríṣun àwòrán, Buharist Reporter/Facebook

Ṣaaju, iroyin to to ni leti ni wi pe ko pẹ ti awọn adigunjale naa rọna wọ inu Banki ọhun lẹyin ti wọn da ọpọ ibọn bo'lẹ lawọn ọlọpaa atawọn ologun de ibẹ.

Ile ifowopamọ First Bank to wa ni agbegbe Mpape nilu Abuja ni iroyin sọ pe awọn adigunjale ọhun ya wọ ti wọn si kọ lati jade pada.

Eeyan kan ti iṣẹlẹ yii ṣoju rẹ koro ni "awọn ọlọpaa ati sọja ti yi ọgba ile ifowopamọ naa ka ti wọn si ti n gbiyanju ati wọ banki naa".

Àkọlé fídíò,

Money transfer: Òdíwọn iye owó tí èèyàn n fi rànṣẹ́ sílé ń dínkù púpọ̀ jù

Adigunjale

Oríṣun àwòrán, OTHER

Iroyin kan sọ pe bi ọkan lara awọn adigunjale ọhun ṣe n gbiyanju lati wa ọna jade sita lo fara gba ọgbẹ ọta ibọn to si n jẹ oro rẹ ninu ile.

Lasiko ti a ko iroyin yii jọ, ohun taa gbọ ni pe awọn oṣiṣẹ alaabo naa ṣi n wa gbogbo ọna lati wọ inu banki naa ki wn le fopin si ikoni nigbekun to n ṣẹlẹ.