Saraki Vs Abdulrazak: Saraki ní òun kò ní gbà kí gómìnà ó yẹ̀yẹ́ bàbá òun

Bukola Saraki ati Abdulrahman Abdulrazak

Oríṣun àwòrán, Saraki/Abdulrazak/twitter

Olori ile aṣofin agba Naijiria nigba kan, Bukola Saraki ti sọ pe gomina ipinlẹ Kwara , Abdurahman Abdulrazak ti gun igi kọja ewe pẹlu igbesẹ to n gbe lati gba ilẹ kan to jẹ ti baba oun.

Ilẹ naa to wa ni ojule kinni, ikẹta, ati ikarun ni opopona Ilofa, GRA, nilu Ilorin ni gbogbo eniyan mọ si Ile Arugbo.

Saraki sọ pe gbogbo igbesẹ gomina jẹ igbiyanju lati pa iṣẹ rere ti baba oun ṣe silẹ run ni.

Ninu atẹjade kan to fi sita, o sọ pe: "Wọn pin ilẹ naa fun baba mi labẹ orukọ ọkan ninu awọn ileeṣẹ rẹ, Asa Investment Limited, ọna totọ si ni ilẹ naa fi di ti baba mi tako nkan ti gomina sọ."

Igbesẹ gomina fihan wi pe ẹsan lo fẹ ẹ gba, ko ni ifẹ awọn eniyan ipinlẹ Kwara lọkan. O jẹ iyalẹnu pe ko ri ilẹ kankan lara awọn to wa ni ibi pataki nilu Ilọrin lati lo fun iwa gbigbẹsan rẹ, ayafi eyi to jẹ ti oloogbe Olusola Saraki."

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Saraki sọ wi pe oun ko ni i gba ki gomina naa o ba iṣẹ baba oun jẹ, tabi ko yẹyẹ baba oun. O ni gbogbo ọna ti ofin la kalẹ ni oun yoo fi koju ọrọ naa, ti awọn yoo si jọ fa a de ibi to ni apẹẹrẹ.

Lọjọbọ to kọja ni Gomina Abdulrazak kede pe ijọba ti gba ilẹ naa pada.

Ninu ikede kan to fi sita ni oju opo Twitter, gomina sọ pe eto ti wa ninu eto iṣuna ọdun 2020 fun ipinlẹ Kwara, lati fi ilẹ naa kọ ọọfisi ijọba.

Oríṣun àwòrán, Abdulrahman abdulrazak/twitter

Àkọlé àwòrán,

Àwòrán ọ́fíisì tuntun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara fẹ́ ẹ̀ kọ́ sórí ilẹ̀ nàá.

"Ilẹ nla to paala pẹlu ileewosan awọn oṣiṣẹ ijọba nilu Ilọrin, ti wọn ya sọtọ lati fi kọ ọọfiisi ijọba, ati aaye igbọkọsi fun ileewosan naa, ṣugbọn ti wọn fi ọna aitọ fun ileeṣẹ Asa Investment Limited, lai si ẹri pe wọn sanwo, lati gba pada l'agbara Ọlọrun."

Gomina tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, kikọ ọọfisi ijọba si ori ilẹ naa yoo fi opin si bi ijọba ṣe n na owo lati gba awọn ile ti ogunlọgọ awọn oṣiṣẹ ijọba n ya a lo lati fi ṣe ọọfisi.