2019: Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019

Aarẹ ati awọn ọmọ Naijiria Image copyright OTHER

Oriṣiriṣi iṣẹlẹ apanilẹrin, arikọgbọn, ibẹru, ati bẹẹbẹ lọ lo ṣẹlẹ ni orilẹede Naijiria ni ọdun 2019. Eyi ni akojọpọ diẹ lara awọn iṣẹlẹ naa.

Busola Dakolo Vs Biodun Fatoyinbo

Gbajugbaja ayaworan, to tun jẹ iyawo gbajugbaja akọrin, Timi Dakolo, Busola Dakolo, fi ẹsun kan pasitọ ijọ Commonwealth of Zion Assembly, Biodun Fatoyinbo, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe o fi ipa ba oun lopọ lọdun diẹ sẹyin.

Lẹyin awuyewuye tó tẹle ifòròwanilẹnuwo naa, pasitọ ọhun ti ni oun yoo gba ile ẹjọ lọ lori ọrọ naa.

Fatoyinbo ni, irọ pọnbele ni ẹsun Busola Dakolo, ati wi pe yatọ si iṣẹ oun gẹgẹ bii pasitọ, oun ko ba arabinrin naa ni nkankan pọ ni ikọkọ oun ko si fi ipa ba obinrin kankan lo pọ ri.

Ẹsun naa gba gbogbo ori ayelujara kan, ṣugbọn Fatoyinbo ni oun ko fipa ba obinrin kankan lo pọ ri.

Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ Naijiria kan sẹ iwọde lọ si ile ijọsin COZA ni Abuja, Eko, ati Port Harcourt

Ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo naa, Busola ni igba ti oun wa ni ileewe girama, ni oun kọkọ pade Fatoyinbo ni Ilorin, Ipinlẹ Kwara, nigba to ṣẹṣẹ bẹrẹ ijọ COZA.

O sọ ninu ẹsun rẹ ti fidio Y! NaijaTV gbe sita wi pe, igba meji ọtọọtọ ni pasitọ naa fipa ba oun lo pọ.

Niṣe ni awọn ọmọ Naijiria kan tu jade ti wọn si fi ẹhonu han lọ si awọn ẹka ijọ COZA ni Eko ati Port-Harcourt. to fi mọ ti Abuja. Wọn pe fun ifipo silẹ Fatoyinbo.

AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ

Ìlú tí ọ̀daràn bá tí dẹ́ṣẹ̀ ló yẹ kí wọn tí gbẹjọ́ rẹ̀ -Agbẹjọ́rò

Ọkọ mi kò le f'ipá bá ẹnikẹ́ni lò pọ̀ láíláí - Modele Fatoyinbo

COZA: Mi ò fípá bá obìrin lò pọ̀ rí láyé mi - Pásítọ̀ Fatoyinbo

‘Ilé ẹjọ́ kò gbé ẹ̀sùn ìfipánílòpọ̀ yẹ̀wò, à ń lọ sí ilé ẹjọ́ - Busola Dakolo

Agbẹjọro fun Busola Dakolo ti ni awọn n gbe Biodun Fatoyinbo lọ si ile ọjọ kotẹmilọrun lẹyin ti ile ẹjọ da ẹjọ ifipanilopọ to pe naa danu.

------------------------------------------------------------

Igbeyawo ofege laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati Hajiya Sadiya Umar Farouq

Oriṣiiriṣi aworan ati akọle to pani lẹrin lo kun ori ayelujara ni eyi ti awọn eniyan fi n ṣeto ipalẹmọ igbeyawo ofege ti wọn ni o yẹ ko waye laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati Hajiya Sadiya Umar Farouq.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Lẹyin to ti hande pe iroyin ẹlẹjẹ ni igbeyawo aarẹ Buhari ti awọn eeyan n pariwo lori ayelujara; sibẹ ọpọ aworan to panilẹrin fun ipalẹmọ lo kun ayelujara bayii

Ṣaaju ni iroyin ẹlẹjẹ ti gba ori ayelujara pe eto igbeyawo naa yoo waye laarin minista tuntun fun Abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede ati aarẹ Naijiria.

AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ

Taló ya fídíò ibi tí Aisha Buhari ti ń bínú ní Aso Rock?

Ìròyìn nípa ìyàwó túntún fún ọkọ mi kò mì mí lọ́kàn rárá-Aisha Buhari

Èrò yapa ní mọ́ṣáláṣí Jimọ̀h láti wá fójú lóúnjẹ lórí ìgbéyàwó òfegè Buhari.

Koda, wọn ṣe idasilẹ 'hashtag #BUSA2019' fun eto igbeyawo irọ naa. Ti ọpọlọpọ aworan apanilẹrin nipa 'igbeyawo naa' si kun ori ayelujara.

Ninu gbogbo iṣẹlẹ iroyin igbeyawo ofege Aarẹ Buhari yii ni fidio kan ti n tan kalẹ pe wọn ti ti Aisha Buhari mọle ninu ile ijọba ni Abuja.

Ṣugbọn ileeṣẹ aarẹ sọ wi pe irọ ni iroyin igbeyawo naa.

---------------------------------------------------------------------------------------------------------------

Naira Marley rẹwọn he, o gba ipo kinni lori Google Trend

Afeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley jẹ gbajugbaja akọrin takasufe lorilẹede Naijiria.

Lọwọ ti a wa yii, Naira Marley ti fẹẹ di oriṣa akunlẹbọ fun ọpọlọpọ awọn ọdọ. Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú Naira Marley di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ ní 2019

Image copyright Naira Marley/twitter

Iroyin ti o jadi laipẹ yii sọ pe oun ni ọmọ Naijiria ti awọn eeyan ṣe afẹri rẹ ju lọ loju opo Google lọdun 2019.

AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ

Ta ni Naira Marley jẹ́ gan?

Ìgbẹ́jọ́ Naira Marley sún síwájú bí àwọn agbẹjọ́rò ṣe ń jà sí àga ìjókòó

Kí ló dé tí Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Naira Marley sí ọ̀la?

'Soapy', àwo orin tuntun Naira Marley tó ń milẹ̀ tìtì

Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Naira Marley yóò ti wo ìbúra Buhari ní May 29

Naira Marley gba ipò mọ́ Atiku lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí èèyàn tí wọ́n ń wá jùlọ ní Google lọ́dún 2019

Ni oṣu karun ọdun 2019 ni akọrin ara, Simi pariwo sita lori ikanni ayelujara lati koro oju si bi awọn ọdọ ṣe n kan si agbami iwa jibiti ori ayelujara.

Eyi si fa itahunsira laarin oun ati Naira Marley.

Naira Marley koju ija si Ruggedman

Kii ṣe Simi nikan ni Naira Marley ba wọ iya ija lori ọrọ boya jibiti ori ayelujara, yahoo-yahoo tọna paapaa julọ lẹyin orin 'Am I a yahoo boy?' to gbe sita.

Ọkan lara awọn odu asọrọdorin lorilẹede Naijiria, Ruggedman pẹlu sọ si ọrọ naa ninu eyi to ti ni ko dara ki awọn olorin, gẹgẹ bi awokọṣe lawujọ o maa gbe lẹyin awọn oni yahooyahoo.

Eyi ko dun mọ Naira Marley ninu, o si fi esi ọrọ kobakungbe ranṣẹ sii lori ayelujara. Koda awọn ololufẹ Naira Marley kan tilẹ kọlu Ruggedman ni ilu Gẹẹsi lori ọrọ yii gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.

Ni ọjọ kẹwa oṣu karun un ọdun 2019 lawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC mu Naira Marley niluu Eko. Ẹsun mọkanla ni wọn fi kan an eyi to da lori gbigbimọ pọ lati huwa ibi, ninu ayederu kaadi igbawo lọwọ pẹlu iwa jibiti.

Lẹyin to lo ọpọlọpọ ọsẹ ni ọdọ awọn ajọ EFCC ni ile ẹjọ gba oniduro rẹ.

Lati igba ti ọrọ igbẹjọ rẹ naa ti bẹrẹ lo si ti di gbajugbaja ni aarin awọn ọdọ, paapaa julọ awọn to rii gẹgẹ bii ẹni to n ja fun awọn ọdọ nitori aarin awọn ọdọ ni yahoo-yahoo pọ si julọ.

Ariwo Marlian! Marlian !! lo gbode kan bayii.

------------------------------------------------------------------------------------------------------------------

Liz Anjorin Vs Toyin Abraham

Image copyright @trafficwaka

Laipẹ yii ni ija bẹ silẹ laarin oṣerebinrin meji naa, Toyin ati Liz. Ija ọhun bẹrẹ ni igba ti Lizzy Anjorin fi fidio kan sita l'oju opo instagram rẹ, nibi ti o ti fi ọpọlọpọ eebu ranṣẹ si Toyin.

Ọrọ naa da awuyewuye silẹ ti Toyin si sọ pe oun fi ọrọ yii lọ agbejẹro rẹ, Legal House Solicitors.

AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ

Niṣe ni awọn ololufẹ awọn oṣere mejeeji ọhun gbe ọrọ ija naa ru sori.

Lẹyin eyi ni awọn agba ọjẹ ninu iṣẹ oṣere nilẹ Yoruba bii Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọrọ lori ija naa, wọn si gbiyanju lati dasi i.

----------------------------------------------------------------------------------

Wọn fi ẹ̀ṣẹ́ ja irawọ Anthony Joshua, o tun fi ẹ̀ṣẹ́ gba a pada

Erongba abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ ile Gẹẹsi ati Naijiria, Anthony Joshua, lati fi irawọ kun irawọ rẹ nilẹ Amẹrika ja si pabo ni ibẹrẹ ọdun 2019.

Image copyright Getty Images

Joshua to ti gba ami ẹyẹ to ga ju lagbo ere idaraya ẹṣẹ kikan lagbaye lẹẹmẹta ọtọọtọ fidirẹmi, to si jẹ iya ajẹbolori lọwọ ẹni ti ko to o, Andy Ruiz lasiko ti wọn koju ara wọn ni Madison Square Garden.

AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ

Ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni Ruiz fi ẹsẹ kan Joshua mọlẹ lai le dide. Eyi lo si mu ko gba ami ẹyẹ nla mẹta, World Boxing Association, International Boxing Federation and World Boxing Organization.

Ṣugbọn nigba ti wọn tun jọ pada ja ninu oṣu Kejila, Anthony Joshua gba igbanu ogo rẹ pada lẹyin to bori Andy Ruiz ninu idije ẹṣẹ kikan to waye ni lu Riyadh ni Saudi Arabi.

Sotitobire Miracle Centre

Ka ma gbagbe, iṣẹlẹ kan wa to ti bẹrẹ si ni gbode lati bii oṣu melo sẹyin ni ilu Akurẹ ipinlẹ Ondo ni ijọ Sotitobire Miracle Centre nibi ti ọmọ ọdun kan, Gold ti dede poora titi di akoko yii.

Lẹyin ọpọlọpọ iṣẹlẹ alatamọ to ti rọ mọ eyi, Pasitọ ijọ naa ṣaa ti wa latimọle titi di dun to mbọ bayii.

AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSotitobire church: Àwọn ọ̀dọ́ ilu dáná sun ilé ìjọsìn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSotitobire church: Àwọn ọ̀dọ́ ilu dáná sun ilé ìjọsìn

----------------------------------------------------------------------------------------------------------------

#Sex for Grade

Iṣẹlẹ miran to tun mi igboro Naijiria ni ti fidio iwadii ikọkọ kan ti BBC Africa Eye ṣe lori awọn olukọ fasiti to maa n beere fun ibalopọ lọwọ awọn akẹkọọ obinrin, ki wn o to o fun wọn ni maaki gidi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfrica Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́