2020: Ọdun 2020 yii ko nìí nira fún àwọn tó bá bẹ̀rù Olorun

2020: Ọdun 2020 yii ko nìí nira fún àwọn tó bá bẹ̀rù Olorun

Aafa bẹ Olorun pe ko ṣe 2020 ni ọdun irọrun fun gbogbo wa- Sheikh Yahaya.

Ọdun 2020 lo tun ti wọlẹ de wẹrẹ ni eyi ti onikaluku n dupẹ ẹ̀mí pe awọn ri.

Gbogbo ijọ Olorun ni o ti n gbadura pe ayọ ati alaafia inu odun naa ni ko jẹ ipin awọn eniyan.

Chief Imam Sheikh Yahaya Oshoala to n dari mọṣalaṣi Oriwu Central, ni Ikorodu ni ipinlẹ Eko ni guusu Naijiria naa gbadura ọdun fun gbogbo wa pe... ayọ ni 2020 a ja si.

Sheikh Samadaani gba awọn olori ni imọran lati ṣe ohun to dara ki ọkan awọn eniyan le balẹ.

Bakan naa ni Aafa nla yii rọ awọn eniyan lati tẹpa mọ iṣẹ ki ilepa ati erongba wọn lọdun tuntun le wa si imuṣẹ.