2019 in retrospect: Ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú dínkù lọ̀dún 2019

oko ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Emi to sonu ninu ijamba oko ofurufu dinku ni agbaye lodun 2019

Iwadii fihan pe odiwọn ẹmi to sọnu ninu ijamba ọkọ ofurufu ni gbogbo agbaye lọdun 2019 dinku gan an ni

Esi iwadii naa fihan pe ida aadọta ninu ọgọrun un ni o fi dinku.

Eniyan mẹtadinlogọta o le ni igba lo ku yatọ si ti ọdun 2018 to jẹ eniyan mẹrinlelọgbọn o le ni ẹẹdẹgbẹrun kan.

Ileeṣẹ Transport Co To70 ni iye nọmba naa dinku pẹlu ijamba Boeing 737 Max Àwọn wo gan an ló wà nínú bàálù Ethiopia tó já ni Nairobi? to ṣẹlẹ ni Ethiopia loṣu kẹta, ọdun 2019Lẹ́yìn tórí yọọ́ nínú ìjambà ọkọ̀; Ọ̀jọ̀gbọ̀n Pius Adesanmi kú nínú ìjàmbá bàálù Ethiopia!.

Iwadii yii tun fihan pe odiwọn irinajo pẹlu ọkọ ofurufu lọdun 2019 pọ sii ṣugbọn ijamba dinku jọjọ paapaa eyi to la ẹmi lọ.

Àkọlé fídíò,

Awọn ero s'ọrọ lori ohun to ṣ'okunfa ijamba baluu Dana

Iṣẹ iwadii yii fihan pe ijamba ọkọ oju irin mẹrindinlaadọrun un ṣẹlẹ pẹl\u ọkọ oju irin makero mẹjọ ninu eyi ti ẹmi mẹtadinlọgọta le ni igba ti sọnu.

Dutch Shipping company ṣalaye pe awọn ẹmi to sọnu yii jẹ lati inu ijamba ọkọ akero.

Àkọlé fídíò,

Ijamba ọkọ le m'ẹmi lọ

Iwadii naa tun ni o le miliọnu marun un ọkọ oju irin ti wọn ṣe jade lọdun 2019.

Aviation Safety Network ni 2018 mu ẹmi ọpọ lọ ninu ijamba ọkọ ofurufu.

O ni ọgọjọ ijamba ṣẹlẹ to mu ẹmi o le ni ẹẹdẹgbẹrun eeyan lọ.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Boing 737 Max of Lion ja ni oṣu kẹwaa, ọdun 2018 ni eyi ti ọpọ ẹmi sọnu

Iwadii naa tun ṣafihan awọn iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu to nii ṣe pẹlu awọn ọkọ ofurufu ọmọ ogun .

Bayii, wọn ti n risi ipese eto aabo lori ofurufu siii ni agbaye ni eyi to tun n ko ipa rere sii.

Àkọlé fídíò,

Yoruba language: Ọdún 2020 to wọlẹ́ dé yìí á tu gbogbo wa lára