Tí mo bá ti ji pátá, o ní àwọn ti mò ń kó o fún- Chukwajekwu Eziigbo

Pata

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Tí mo bá ti ji pátá, o ní àwọn ti mò ń ko fún- Chukwajekwu Eziigbo

Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kínní, ọdun 2020, ni déedé ààgo mẹ́jọ ní àwọn ọlọpàá láti Ojo wá mú Chukwajekwu Eziigbo.

Chukwu jẹ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dogun idi ti wọn si fi wa muu ni nítori pé o jí pátá lóri ìkọ ti wọ́n sá aṣọ si.

Afura si òun jẹ́wọ pé o ti to odidi ọdun kan gbáko ti òun ti ń ji páta ní àwọn orisirisi ilé ni àdúgbò náà.

Àkọlé fídíò,

Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

O ní òun máa n mú àwọn páta ti òun ba ti jí lọ fun Chidima Obietuake ẹni ọdun mẹtadinlogun, Chikwaka Chidima, Gold Enyinnaya ẹni ọdunnmẹtalelogun àti Akomas Amarachi ẹni ọdún mẹrindinlọgbọ̀n ti gbogbo wọ́n ń gbé àgbègbè Ojo.

Gbogbo àwọn afurasi yìí ni wọ́n mu ti wọ́n si ti jẹ́wọ pé lóòtọ ni àwọn ji páta, bákan náà ni ọlọpàá gba àwọn páta míràn ti wọ́n ti ji sílẹ̀ lọ́wọ́ wọ́n.

Àkọlé àwòrán,

Pata ti ọlọpàá gbà lọ́wọ́ àwọn afura si

Ilé iṣẹ́ ọlọpàá ni ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́, gbogbo àwọn afurasi náà ni yóò sì fojú ba ilé ẹjọ

Àkọlé fídíò,

Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré