Amotekun fi hàn pé ìpòngbẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà ti d'ókè

Ọjọgbọn Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbajugbaja alami ẹyẹ imọ Litiresọ, Ọjọgbọn Wole Soyinka ti kede atilẹyin tirẹ naa fun ikọ alaabo fun ẹkun Iwọ Oorun Naijiria ti a mọ si 'Amotekun'.

Soyinka ṣapejuwe ikọ alaabo naa gẹgẹ bi ẹbun ọdun to dara gan an, o ni eyi ti fihan pe ipongbẹ awọn ọmọ Naijiria ti bori.

Ninu ọrọ rẹ nilu Eko nibi ipade kan lọjọ Aje pẹlu awọn agbaagba ati eekan orilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Soyinka ni eyi fọkan ẹni balẹ ni iranti atunbọtan ogun to waye to si pari ninu oṣu kinni, ọdun 1970 to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn iṣẹlẹ manigbagbe to buru jai kaakiri agbaye.

Ọrọ atilẹyin Ọjọgbọn Soyinka yii wa lẹyin ọjọ mẹrin ti awọn gomina iha Guusu-Iwọ Oorun ppkorajọ nilu Ibadan lati ṣe ifilọlẹ ikọ Amotekun naa.

Ẹwẹ, ṣiṣi aṣọ loju ikọ alaabo yii ti n ru ọpọlọpọ ikunsinu, igboriyin, gbọyi s'ọyi, atilẹyin sita lorilẹ-ede Naijiria ati kaakiri agbaye.

Awọn to ti n ṣatilẹyin fun ikọ Amotekun

Ẹgbẹ awọn agbẹjọrọ Naijiria ti a mọ si Nigeria Bar Association, ẹka ti ipinlẹ Ekiti ni awọn gomina iwọ oorun guusu Naijiria ko tii ṣe kọja ilana ofin tọdun 1999 ti Naijiria n lo.

Wọn ni idasilẹ Amotekun lati moju to eto aabo ilu ko lodi si ofin Naijiria rara.

Ogbeni Samuel Falade to jẹ alaga ẹka ti Ekiti fun ẹgbẹ agbejọrọ ṣalaye pe abala 214 ati 215 ninu iwe ilana ofin todun 1999 ti Naijiria n lo gbe agbara eto aabo fun awọn agbofinro Naijiria nitootọ.

O ni awọn ọlọpaa lagbara lati pese eto aabo fun ẹmi ati dukia awọn eniyan Naijiria.

Ṣugbọn eyi ko din agbara awọn Gomina ku lati tun wa ọna abayọ ti wọn ba ni iṣoro lori ipese eto aabo fawọna ra ilu ti wọn n dari.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán,

Ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn tí ó bá gbé ìbọn yóò wọ gàù - Ọlọ́pàá Naijiria

Ogbeni Samuel Faleke ṣalaye ni kikun pe abala 14 (2b) ninu ori keji iwe ofin Naijiria fun Aarẹ ati awọn Gomina ni agbara lati pese aabo fawọn ara ilu ni ẹkun ati ipinlẹ koowa wọn.

O tun ni abala ogun ninu iwe iṣamojuto eto idajọ ati iwa ọdaran ni Naijiria faaye gba ara ilu lati mu ole tabi ẹni to huwa ọdaran ki wọn si faa le agbofinro lọwọ bi o ti yẹ.

O ni fun idi eyi, awọn eleto aabo labẹ Amọtẹkun ni agbara lati mu ọdaran ki wọn si fa wọn le ọlọpaa lọwọ.

Samuel to jẹ alaga agbẹjọro ni fun idi eyi, ipese aabo ara ilu pẹlu agbara Gomina ni awọn amọtẹkun ni ati pe gbogbo agbẹjọrọ yoo pese atileyin to yẹ labẹ ofin lati fi ran awọn agbofinro ati awọn Amọtẹkun lọwọ.

Àkọlé fídíò,

Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Ẹranko abìjàwàrà tí kò ṣe é gbeńa wo ojú rẹ̀ ni Àmọ̀tẹ́kùn - Onímọ̀

Ọpọlọpọ nkan rere ni ẹranko amọtẹkun duro fun ni ilẹ Yoruba.

Eleyii to tumọ si ipa ribiribi ti awọn eniyan lero pe ikọ Amọtẹkun ti ilẹ Yoruba yoo ma gbeṣe.

Ọjọgbọn onimọ nipa ẹkọ ati imọ Ede Yoruba, Ọjọgbọn Bisoye Elesin sọ wi pe awọn ogboju ọde ni ilẹ Yoruba ri amọtẹkun gẹgẹ bi ẹrankọ gboogi to ni agbara to si ni okun.

Ọjọgbọn Elesin ni bi o tilẹ je pe awọn ẹranko abija pọ, amọ amotẹkun naa jẹ ọkan ninu awọn ẹrankọ olongbo ti o lagbara.

Kini Yoruba mọ Amọtẹkun si?

  • Akinkanju: Amọtẹkun jẹ ẹranko to ni agbara to si ni igboya, nitorin naa awọn ogboju ọde ninu nikan lo le e koju wọn ninu igbo.
  • Otitọ-inu: Amotẹkun jẹ ẹrankọ to n ṣe otitọ inu, ti yoo ba pa ẹran, kiakia ni yoo pa a lai wo ẹyin, eleyii to yatọ si gbogbo ẹranko to ku paapaa bi kiniun, ti awọn eniyan mọ pé o le kọkọ wo ẹran niran ki ọkan iru ẹran bẹẹ ti balẹ pe o le ma pa oun ki kinihun to wa kọlu.
Àkọlé fídíò,

Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

  • Abijawara: Amotẹkun to jẹ ẹbi ologbo, jẹ ẹranko abija ti ko ṣe e deede gbena woju rẹ, nitori awọn akinkanju ogboju ọdẹ ni o maa n pa wọn ninu igbo.
  • Asọgba: Amọtẹkun maa n ọ ibi to wa, eniyan ko le e deede wọ sakani ibi to wa lai ṣẹ wi pe o jẹ ogboju ọdẹ.

Aarẹ Ọna Kakanfọ ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams to jẹ adari ikọ̀ Amọtẹkun tuntun tó wà fún ètò aàbò ilẹ̀ Yoruba ti wọn ṣẹsẹ fi lọlẹ naa fikun wi pe awọn ṣetan lati ri wi pe awọn adigunjale ati daran ko tun fi ẹmi ọmọ ilẹ Yoruba kankan sofo mọ.

Aarẹ Ọna Kakanfọ ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams ni adari ikọ̀ Amọtẹkun tó wà fún ètò aàbò ilẹ̀ Yoruba.

Ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn tí ó bá gbé ìbọn yóò wọ gàù- Ọlọ́pàá Naijiria

Ile iṣẹ Ọlọpaa ni ẹkun iwọ-oorun Naijiria ti kilọ gidigidi fun ikọ Amọtẹkun lati maṣe tẹ oju ofin mọlẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ipinlẹ to wa ni ilẹ Yoruba yii sọ wi pe awọn ko ni gba fun wọn, ki wọn mu ibọn ilẹwọ dani lati ma a fi ṣe iṣẹ abo ni ilu.

Lẹyin ọpọlọpọ ipaniyan ni ilẹ Yoruba ati eto aabo to mẹhẹ, ni awọn gomina ni ẹkun yii wa ṣe ipade ni ọdun to kọja lati gbe ikọ Amọtẹkun silẹ.

Ilẹ iṣẹ ọlọpaa ni Ekiti, Ogun ati Ondo ti sọ wi pe awọn yoo fi panpẹ ọba mu ẹnikẹni ti awọn ba ba ibọn lọwọ wọn.

Wọn ni o lodi si ọfin ki Ikọ Amọtẹkun gbe ibọn to ba ni ọta ibọn ninu, ti o le e pa eniyan

Aarẹ Ọna Kakanfọ ilẹ Yoruba,Oloye Gani Adams ni adari ikọ̀ Amọtẹkun tó wà fún ètò aàbò ilẹ̀ Yoruba.

Awọn eniyan to parapọ jẹ Amọtẹkun ni ikọ Oodua Peoples Congress, OPC, awọn ẹgbẹ vigilante ni Naijiria, ẹgbẹ awọn apẹran ninu igbo, ẹgbẹ Agbẹkọya ni ẹkun iwọ oorun Naijiria, ẹgbẹ Yoruba Youth Council ati ikọ Community Security Awareness Initiative Corps of Nigeria.

Ọ kere tan, ọkọ to le ni ọgọfa ni awọn gomina ipinlẹ iwọ oorun naa pese fun ikọ amọtẹkun lati jẹ ki wọn le e ṣe iṣẹ wọn bo sẹ tọ ati bo ti yẹ.

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Ọna Kakanfọ ilẹ Yoruba,Oloye Gani Adams ni adari ikọ̀ Amọtẹkun tó wà fún ètò àbò ilẹ̀ Yoruba.

Gomina Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti, to tun jẹ alaga agbarijọpọ awọn gomina orilẹ-ede Naijiria ni Amọtẹkun ko waye lati rọpo awọn ileeṣẹ aabo to n bẹ nilẹ tẹlẹ.

Fayemi ni wọn yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo to ku, ki eto naa le kẹsẹjari, ki awọn olugbe ipinlẹ Yoruba gbogbo le maa fi ẹdọ sori oronro sun.

Àkọlé fídíò,

'Mo fọ́ lójú ṣùgbọ́n mo mọ gbogbo irinṣẹ́ tí mo fi ń ṣe mọkalíìkì'

Amọtẹkun ipinlẹ kọọkan ni yoo maa mojuto ipinlẹ ti wọn pin wọn si lai rekọja lọ si ipinlẹ mii, ayafi ti iṣẹlẹ pajawiri ba waye.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán,

Ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn tí ó bá gbé ìbọn yóò wọ gàù - Ọlọ́pàá Naijiria