Night Rider: Sunny sùn ní nínú ọkọ̀ ìgboro London fún ọdún 21

LONDON Image copyright Venetia Menzies
Àkọlé àwòrán Sunny sùn ní nínú ọkọ̀ ìgboro London fún ọdún 21

O le ni ogun ọdun ti Arakunrin Sunny fi sun si inu ọkọ ni ilu London ni ilẹ Gẹẹsi lẹyin ti ijọba orilẹ-ede naa kọ lati fun un ni aabo ẹni to sa asala fun ẹmi wọn.

Ninu ọkọ akero to ma a n kaakiri ileto kan si omiran ni Sunny ti n sun to n ji pẹlu ọkọ naa ṣe n kaakiri igboro.

Image copyright Sunny

Gẹgẹ bi iṣe rẹ, Sunny yoo duro ni ẹba ọna ni alaalẹ lati duro de ọkọ alẹ to n bo ki oun le wọ inu rẹ.

Bi o ba ṣẹe wọ inu ọkọ naa ni yoo ri oju awakọ ti o mọ, ti yoo si rẹrin si wọn ati awọn ero inu ọkọ.

Sunny yoo fa apo ti o gbe mọran, ti yoo si jọkọ lati forikọ, ki oorun to gbe e lọ.

Image copyright Getty Images

Awọn ẹbi Sunny lo ra itusilẹ rẹ lọ si Ilẹ Gẹẹsi lẹyin ti wọn dajọ iku fun pe o pẹlu awọn ajijagbara to n beere fun iṣejọba tiwatiwa.

Fun ọpọlọpọ ódun ti o fi wa lai ni ile lori, lo fi woye lati pada si ile, amọ ẹru iku ati ọgba ẹwọn lo mu u duro lati ma a gbe ilu ọba gẹgẹ bi alainile lori.

Image copyright Venetia Menzies

Arabinrin kan to jẹ ọmọlẹyin Kristi lo kọkọ n san owo lati wọ ọkọ alẹ naa fun ọpọlọpọ ọdun, ti awọn ọrẹ rẹ yoo tun san owo ohun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Ti o ba di owuro ni Sunny yoo lo ṣiṣẹ iranwọ fun ile ijọsin, ti yoo si ṣe ọpọlọpọ iru iṣẹ bẹẹ, ko to di wi pe yoo gba yara ikawe Westminster Reference Library lọ nibi ti yoo ti wo ohun to n ṣẹlẹ ni agbaye, ti yoo si tun lọ ka iwe ti ko i tii ka pari.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Sunny sùn ní nínú ọkọ̀ ìgboro London fún ọdún 21

Lẹyin yii ni yoo gba ile ounjẹ lọ lati bere boya wọn le e fun oun ni ounjẹ jẹ, ti o si ni o soro ni ọpọ igba ki ẹnikẹni fi ọwọ osi juwe ile fun oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Amọ, ki aago mẹsan alẹ to lu ni arakunrin Sunny yoo ti ma a lọ si ibudo igbọkọ si lati le tun wọ mọtọ alẹ, eleyii ti yoo wa titi di owurọ ọjọ keji.

Image copyright Sunny

Sunny fikun un wi pe awọn ti wọn ko ri ile gbe pọ ni oke okun, ti ọpọlọpọ ninu wọn si jẹ obinrin to le e jẹ ọmọ ilẹ Adulawọ tabi oyinbo to n sa fun iwa ifipabanilopọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIfa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Arakunrin naa ti pe ẹni ọdun marundinlọgọta,55 ni ọdun 2017 ko to ri iwe igbelu gba lẹyin ọpọlọpọ akitiyan fun ọdun kan pẹlu iranwọ lati ọdọ awọn ile ijọsin to ti ṣiṣẹ ati awọn ọlọkọ ti o maa n sun si mọju.

Image copyright Venetia Menzies

Iroyin ayọ ni pe Sunny ti wa di ẹni to ni ile bayii, ti o si le ṣiṣẹ to wu nitori o ti ni iwe igbelu.