2020 Public Holidays: Àwọn ọjọ́ ìsìnmi tó máa wà nínú ọdún 2020 ní Nàìjíríà

onilu

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán,

Isinmi dun pupọ lẹyin iṣẹ!

O kere tan awọn ọmọ Naijiria a gba isinmi fun ọjọ mẹwaa ti a ya sọtọ fun sisami ayẹyẹ ati iranti lọdun 2020.

Ọjọ akọkọ ninu ọdun 2020

Lọdun 2020, ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun ni ọjọ isinmi akọkọ ni eyi ti onikaluku fi sami ayajọ pe oju koowa ri ọdun tuntun.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Ayajọ ọjọ ominira Naijiria: ọjọ kinni, oṣu kẹwaa

Gbogbo orilẹ-ede agbaye lo ni ọjọ ti wọn ya sọtọ ti wọn fi n sami ayẹyẹ ominira wọn kuro lọwọ ijọba amunisin.

Ọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 1060 ni Naijiria gba ominira kuro lọwọ ilẹ Gẹẹṣi to ko wọn lẹru.

Lọdun 2020, isinmi kuro lẹnu iṣẹ maa wa fun awọn eniyan Naijiria lọjọ kinni, oṣu kẹwaa lati fi sami ominira orilẹ-ede wa.

Ayajọ ọjọ Ẹti Rere: ọjọ kẹwaa, oṣu kérin

Ọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, ọdun 2020 ni ayajọ sisami ọjọ Ẹti rere yoo waye ni Naijiria.

Ọjọ yii jẹ eyi ti awọn onigbagbọ maa fi n sami iku Jesu Olugbala lori igi agbelebu nibi agbari.

Ọjọ yii ni wọn gba pe Jesu ku lọwọ Pọntiu Pilatu gẹgẹ bi o ṣe hande ninu Bibeli.

Kaakiri awọn orilẹ-ede agbaye bii Ghana, UK, Cameroon atawọn mii ni wọn ti maa n sami ọjọ yii.

Àkọlé fídíò,

Ọbẹ̀ ni, ẹran ni o, irú oúnjẹ wo lẹ́ fẹ́, ká báa yín sè é wá sílé yín?

Ayajọ ọjọ Ajinde: ọjọ Ajé, ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin:

Eyi ni ọjọ ti awọn onigbagbọ maa n lọ si Galili nibi ti wọn gbagbọ pe Jesu ti kọkọ farahan to fi dagbere fawọn ọmọ ẹyin rẹ pe oun n padabọ wa lẹẹkeji lati wa ko awọn ayanfẹ.

O maa n waye lẹyin ti awọn onigbagbọ ba pari aawẹ ogoji ọjọ ti wọn n pe ni 'Lenth'

Kaakiri agbaye ni awọn eniyan ti maa n gba isinmi ọdun Ajinde Jesu yii.

Isinmi naa maa n jẹ ki onikaluku fi ri aaye sami rẹ ni ọna ti o ba gbagbọ ninu rẹ ni.

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán,

Oriṣirisi ounjẹ aladun naa ni wọn maa n se ti onikaluku fi maa n gbadun isinmi naa.

Ayajọ ọjọ awọn oṣiṣe: ọjọ kinni, oṣu karun un:

Eyi ni ọjọ ti awọn oṣiṣẹ Naijiria ya sọtọ lati fi sami iṣẹ ti wọn n ṣe.

Awọn orilẹ-ede to le ni ọgọrin lo maa n sami ọjọ yii ni ayajọ ọjọ iṣẹ ni agbaye.

Awọn oṣiṣẹ maa n yan bi ologun, awọn alaṣẹ maa n fi ọjọ yii saaba ṣe ikede ohun tuntun ti wọn ba ni fawọn eniyan Naijiria lasiko naa.

Àkọlé fídíò,

Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

Ayajọ ọjọ awọn ewe: ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun un:

Eyi ni ọjọ ti orilẹ-ede Naijiria ya sọtọ lati sami awọn ewe ti wọn jẹ ogo ilẹ wa.

Awọn ọmọde maa lọ yan bi ologun ni awọn papa iṣere kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria ni ọpọ igba.

Awọn ijọ Ọlọrun miran naa maa n lo asiko yii lati bukun awọn ewe ki inu awọn ọmọde le dun.

Eid el-Fitri : ----

Eyi ni ayẹyẹ ọdun pe awọn musulumi pari aawẹ Ramadan fun ọdun 2020.

Awọn musulumi kaakiri agbaye lo maa n sami ayajọ opin aawẹ Ramadan yii ṣugbọn ko i tii si ọjọ kan ni pato fun un lọdun 2020 nitoripe igba ti wọn ba ri oṣù ni aawẹ Ramadan yoo pari.

Ti ọdun 2020 yii ṣeeṣe ko bọ si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun un.

Oríṣun àwòrán, @others

Ayajọ iṣejọba Tiwantiwa- ọjọ kejila, oṣu kẹfa

Lọdun 2019 ni Naijiria paarọ ọjọ sisami ayajọ awa ara wa to maa n waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun un ọdun.

Aarẹ Obasanjọ lo ya ọjọ yii sọto lọdun 2000 lasiko to ṣi wa ninu ijọba.

Wọn yii pada labẹ iṣejọba Aarẹ Buhari si ọjọ kejila, oṣu kẹfa lati fi sami igbiyanju, ijiya ati iku Moshood Kashimaawo Olawale Abiola to dije dupo aarẹ Naijiria.

Lọdun 1993 ni Ibrahim Badamosi Babangida wọgile idibo gbogboogbo ọhun to bi isami ayajọ iṣẹjọba awa ara wa ni Naijiria.

Eid el-Kabir: ọdun Ileya.....

Ọdun Ileya Ed el-Kabir yii jẹ eyi ti awọn musulumi maa n sami ọdun pipa ẹran agbo.

Odun yii ṣe pataki ninu ọdun ti awọn ẹlẹsin Islam maa n ṣe ni eyi ti ọọ maa n sami kaakiri agbaye.

Ọjọ meji ni ijọba Naijiria maa n ya sọtọ fun ayẹyẹ ọdun Ileya.

Ti ọsun yii ṣeeṣe ko bọ si ọgbọn ọjọ ati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila.

O wa fun sisami bi Anabi Ibrahim ṣe pa ẹran agbo dipo Ismail ọmọ rẹ.

Àkọlé àwòrán,

ọdun Keresi jẹ ti ọjọ ibi Jesu Kristi

Ọdun Keresimesi: ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kejila:

Ni gbogbo agbaye ni wọn ti n sami ọjọ keresimesi ni asiko yii.

Awọn ẹlẹsin Kristieni ni wọn fi n sami ayẹyẹ ọjọ ibi Jesu Kristi.

Ni Naijiria, awọn ọmọde maa n wọ awọn fila ọdun, jingi oju, atawọn nkan iṣere miran lasiko yii.

Ọjọ pipaarọ ẹbun 'Boxing Day' : ọjẹ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila

O jẹ ọjọ ti wọn maa n ṣe paṣipaarọ ẹbun laarin awọn Kristiẹni.

Awọn miran gba pe ọjọ pinpin ẹbun fun awọn alaini, opo ati awọn ẹbi ni.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà