Imam tó fẹ́ ọkùnrin míì níyàwó forí kó ìjìyà òfin

Imam ati iyawo to di ọkunrin

Oríṣun àwòrán, Daily Monitor

Àkọlé àwòrán,

A ṣe ọkunrin to n fi Hijab bori ni Imam gbe ni iyawo sile

Imam kan to ti n ro wi pe obinrin loun gbe niyawo ni wọn ti yọ kuro lori oye rẹ gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Monitor ṣe jabọ.

O ba Sheikh Mohammed Mutumba lojiji lẹyin ọsẹ meji igbeyawo wọn lati ri i pe ọkunrin ni iyawo oun, Swabullah Nabukeera to tin n wọ hijab lati ọjọ yii ati wi pe orukọ rẹ gangan ni Richard Tumushabe.

Aṣiri yii tu sita nigba ti awọn ọlọpaa orilẹ-ede Uganda mu Tumushabe nigba ti wọn fura pe o ji ẹrọ amohunmaworan ati aṣọ awọn aladugbo wọn nile ti oun ati ọkọ rẹ n gbe.

Gẹgẹ bi iṣe awọn ọlọpaa, ọlọpaa obinrin yẹ ara afurasi yii wo finifini ki wọn to mu u lọ si ẹwọn.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun ọlọpaa naa lati ri i pe o di aṣọ sinu kọmu rẹ lati fi ṣe bii pe ọmu rẹ ni.

Iroyin naa ni pe Sheikh Mutumba to jẹ Imam ni Mọṣalaṣi ilu Kyampisi ni Kampala, olu ilu orilẹ-ede Uganda ko tii ba iyawo rẹ lajọṣepọ kankan tori pe o ni oun n ṣe nkan oṣu lọwọ.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Nitori eyi, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fi ẹsun ki eeyan dibọn bii ẹlomiran, ole jija ati kiko nkan pẹlu idanimọ ẹlomiran.

Iwe iroyin Daily Moitor royin pe Sheikh Abdul Noor Kakande to jẹ adajọ agba Musulumi (regional kadhi) fun ẹkun naa sọ pe iṣẹlẹ naa ṣe ni laanu jọjọ awn si ti n ṣewadi Imam naa.

Bakan naa, wọn royin gẹgẹ bi Sheikh Isa Busuulwa to jẹ Imam Mọṣalaṣi ti Sheikh Mutumba ti n waasu pe wọn ti jawe lọ gbele ẹ fun un lati lee da abo bo ofin ẹsin Islam.

Àkọlé fídíò,

Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Fun ọjọ mẹrin, iwe iroyin Daily Monitor fabọ jẹni pe Sheikh Mutumba ko tii si nile.

Eeyan kan ti ko fẹ darukọ rẹ sọ pe "iṣẹlẹ naa da a lagara gan o si nilo imọran gidi".

Àkọlé fídíò,

Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'