Nigerian Senate: Éló ni N2Miliọ̀nù owó àjẹmọ́nú Kérésì tẹ́ẹ fi ń gún wa lọ́wọ́?

Ile igbimọ aṣofin agba Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate

Ki la fẹ fi miliọnu meji naira pere ṣe gẹ́gẹ́ bi owo ajẹmnu ọdun keresimesi ti ẹ fi gun wa lọwọ?

Awọn sẹnetọ kọọkan tilẹ ṣapejuwe iye owo naa eyi to jẹ diẹ lara awọn owo to ma n bọ si wọn lọwọ gẹgẹ bi horo omi to kan kan sinu agbami okun nla inawo asiko ọdun.

Awọn mii ni bi adari ile igbimọ aṣofin agba ba ṣe b de pada bayii lẹnu isinmi loṣu yii lawọn ko ni jẹ ko ni isinmi kankan.

"Owo ti ko to gbọ bukata asiko ọdun keresimesi wa," ni sẹnetọ kan sọ. Koda awa kan ti n korajọ lati wa fi ẹj yii sun aarẹ.

Gẹg bi awọn sẹnetọ meji kan ṣe sọ ọ fun iwe iroyin Premium times, wọn ni awọn gba iroyin alaati pe owo wọle si apo isuna wọn lati ẹka eto isuna ile igbimọ aṣofin agba ti wọn si ri i pe miliọnu meji naira pere ni.

Wọn ni ko si eredi owo naa ninu alaati ti awọn gba ṣugbọn wọn ti sọ fun wọn ni ọjọ diẹ ṣaaju pe ki wọn maa reti owo ajẹmọnu keresi wọn.

Awọn sẹnetọ yii ko fẹ foju han ṣugbọn wọn ni ko si igba ti awọ́n ko ni ṣe bẹẹ bi ibinu awọn ba ru soke sii.

Ọkan lara wọn bu ẹnu atẹ lu ọrọ pe adari ile igbimọ aṣofin Ahmed Lawan kuna lati ni oye awọn nkan to maa n koju wọn ti wọn ba lọ bẹ ẹkun ti wọn n ṣoju wo.

"Ọpọlọpọ ijọba ibilẹ lo wa labẹ ẹkun ti mo n ṣoju. Bawo ni mo ṣe fẹ sọ fun wọn pe miliọnu meji naira pere ni mo mu wale?".

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Sẹnetọ naa fi kun un wi pe "koda bi mo ba kan n rinrin ajo lati lọ ṣebẹwo si ẹkun idibo mi, aadọta miliọnu naira ni mo maa n mu dani".

Sẹnetọ mii ni owo gbọi ni awọn aṣofin maa n gba fun ọdun keresi ko wa ye bi iṣejọba ti ile aṣofin tọtẹ yii pẹlu ajọṣepọ wọn ati ẹka alaṣẹ ṣe wa n pin owo kekere.

"A ti n tiraka ninu iṣẹ lati igba taa ti bẹrẹ iṣejọba ile aṣofin eleyii bẹẹ si ni gbogbo atilẹyin to yẹ la n fun iṣejọba yii, ṣe lawn eeyan n binu si wa lori ayelujara pe oju kan la kan wa".

Wọn ni labẹ ijọba ile aṣofin keje, awọn maa n gba ju miliọnu meji lọ fun ọdun keresi ati ọdun Sallah.

Ọkan lara awọn Sẹnetọ naa ni "miliọnu meji naira lee kere o ṣugbọn maa gba wọn nimran lati ranti ọgọọrọ ọmọ Naijiria ti ko tilẹ lee gba kolobo lara iye owo yẹn fun ọdun kan.