Taa ni Hope Uzodinma tí ilé ẹjọ kéde gẹ́gẹ́ bí Gómìnà tuntun ìpínlẹ̀ Imo

aworan Hope Uzodinma

Oríṣun àwòrán, Hope Uzodinma/Facebook

Odu ni Sẹnẹtọ Hope Uzodinma lagbo oṣelu Naijiria,kii ṣe aimọ foloko.

Saaju ki ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria to dajọ pe oun lo jaweolubori ninu idibo Gomina ni ipinlẹ Imo lọdun 2019,o ti gbiyanju lati jẹ Gomina ni ọdun 2003.

Ninu awọn oloṣelu to ti tọ ile ọkọ awọn ẹgbẹ oṣelu lorisirisi wo,Hope Uzodinma ti fi igba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati Alliance for Democracy,AD.

Yatọ si ipa to ko lagbo oṣelu,gbajugbaja olokoowo ni Uzodinma ti o si pẹka jakejado Naijiria .

Ni agbegbe Orlu to ti wa ,wọn fi jẹ oye Onwa Netiri ti ilu Omuma .

Hope Uzodinma ko ṣeṣe ma lọ si ile ẹjọ lati gba ẹtọ rẹ

Lasiko tawọn eeyan n jẹri niwaju igbimọ adajọ Chukwudifu Oputa lọdun 2001,wọn fẹsun kan Hope Uzodinma pe nigba to wa ni ileeṣẹ to n ṣeto irinajo ori omi,NMA, o fi ọna eru fowo ranṣẹ si olori ijọba ologun Abdulsalam Abubakar .

Bẹẹ naa ni a ri akọsilẹ pe wọn fi ẹsun kan pe Dere Awosika to jẹ wọlewọde iyawo aarẹ ana Stella Obasanjo gbe iṣẹ agbaṣe fun Hope Uzodinma lọna aitọ.

Oríṣun àwòrán, Hope Uzodinma

Koda o tun fi igba kan jẹjẹ lọdọ ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra EFCC to

Lagbo oṣelu o ṣe ẹjọ de ile ẹjọ giga lori boya o kaju oṣunwọn lati jẹ Sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun idibo Iwọ orun ipinlẹ Imo.

Lẹyin ọpọ awijare ati atotonu ile ẹjọ to gajulọ lọjọ kaarun oṣu kaarun ọdun 2011 fi idajọ lelẹ pe Uzodinma ni oludije ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi lelẹ ti o si jaweolubori ninu idibo to waye.

Irinajo rẹ de ipo Gomina Imo

Ninu idibo Gomina ipinlẹ Imo to waye lọdun 2019,Hope Uzodinma ati awọn oludije miran jijọ waako pẹlu Emeka Ihedioha fun ipo Gomina.

Ninu abajade idibo naa Ihedioha ni Inec kede gẹgẹ bi ẹni to jaweolubori ti Hope Uzodinma si ṣe ipo kẹrin.

Àkọlé àwòrán,

Fada Mbaka kéde pé ẹ̀mí mímọ́ ti kọ Ihedioha bíi gómìnà Imo

Esi yi ko tẹ Uzodinma lọrun ti o si gbe ọrọ naa lọ si iwaju ile ẹjọ.

Idajo to papa gbe ogo fun leleyi to waye lọjọ kẹrinla oṣu Kini ọdun 2020 nibi ti awọn adajọ ile ẹjọ giga ti ni ki Inec fun ni iwe aṣẹ gẹgẹ bi ẹni to yẹ ni Gomina.

Hope Uzodinma ni Gomina ẹlẹẹkaarun ti yoo jẹ ni Imo lati igba ti eto ijọba awarawa ti bẹrẹ ni ọdun 1999.

Emeka Ihedioha: Wo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa Gomina Imo ti ilé ẹjọ́ giga ye àga mọ́ nídí

Àkọlé àwòrán,

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Naijiria ti kéde pé òfo ni ibo to gbe gomina ipinlẹ Imo, Emeka Iheodiha wọle.

Ọjọ Kẹrinla, osu kinni, ọdun 2020 ni ile ẹjọ to gajulọ lorilẹ-ede Naijiria yẹ aga mọ Gomina ipinlẹ Imo, Emeka Ihedioha ni idi, ti wọn si kede Hope Uzodima gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo gomina ni ọdun 2019.

Ile ẹjọ giga julọ naa ni idi ti awọn fi yọ Emeka Ihedioha ni gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Imo ni wi pe ko oun kọ lo ni ibo to pọ julọ ninu idibo sipo gomina to waye ni Osu Kẹta, ọdun to kọja.

Ihedioha ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo to to 273,404 nigba ti Hope Uzodinma ti ẹgbẹ oṣelu APC ni ibo to to 96,458.

Ẹni ti ile ẹjọ sọ wi pe oun lo wọle lo ṣe ipo kẹrin lasiko ti Ajọ Eleto idibo INEC kede rẹ lasiko idibo naa.

Bi esi idiboti INEC kede ni Osu kẹta, ọdun 2019 ṣe lọ

PDP: Ihedioha Emeka 273,404

AA: Uche Nwosu 190,364

APGA: Ifeanyi Ararume 114,676

APC: Hope Uzodinma 96,458

YPP: Ikedi Ohakim 527

Ile ejọ naa ti pe fun ki wọn gba iwe eri to gbe e wọle, ki wọn si fun Hope Uzodinma gẹgẹ bi ẹni ti awọn eniyan dibo yan lasiko idibo naa.

Àkọlé fídíò,

BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Wo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa Gomina Imo ti ilé ẹjọ́ giga ye àga mọ́ nídí

  • Ọjọ Kẹrindinlogun, ọdun 1965 ni wọn bi Gomina to lọ naa ni agbeegbe ijọba ibilẹ Mbutu Aboh Mbaise ni ipinlẹ imọ, to wa ni Ila Oorun orilẹede Naijiria
  • Ebere Ihedioha ni iyawo Emeka, ti wọn si ni ọmọ mẹrin Emeka, Ezinwa, Nkem ati Kamsi.
  • Ile iwe giga fasiti ti ilu Eko ni Akoka-Yaba ni ipinlẹ Eko ni o ti lọ si ile iwe giga, nibi ti o ti kawe gba oye imọ ijinlẹ sayẹnsi nipa ounjẹ ati imọ ẹrọ, Food Science and Technology ni ọdun 1988
  • O ti wa ni ipo Igbakeji Abẹnugan Ile Igbimọ Asofin Agba lorilẹ-ede Naijiria ri
  • Ni Ọjọ kọkanla, Osu kẹta, ọdun 2019 ni Ajọ Eleto Idibo kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo gomina to waye naa.
Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí