EFCC: Ilé ẹjọ́ rán ọmọ ìjọ lẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó jí ₦15m owo ìjọ

EFCC Image copyright EFCC/TWITTER
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ rán ọmọ ìjọ lẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó jí ₦ 15m owo ìjọ

Akapo ijọ kan ti ri ẹwọn ọdun mejidinlogun he lẹyin ti wọn fi ẹsun kan an pe oji miliọnu mẹẹdọgbọn dọla ti o wa fun igbelarugẹ ijọ naa.

Arakunrin Ibrahim Aku lati ijọ Church of Brethren ni ipinlẹ Adamawa ni o gba wi pe oun jẹbi ẹsun onigun mẹfa lilo owo ni ponpo ati ole jija.

Lẹyin eyi ni ile ẹjọ wa ran an l si ẹwọn ọdun mẹta fun ẹsun kọọkan, eyi to jasi ẹwọn ọdun mejidinlogun.

Ikọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra, EFCC lo fi iroyin naa si oju opo rẹ lori Twitter pẹlu aworan ọdaran naa ti ile ẹjọ ni ariwa orilẹ-ede Naijiria ran lọ si ẹwọn naa.

Ile ẹjọ ri ẹri daju pe wọn fun akapo ijọ naa ni owo lati fi pamọ fun ijọ naa, ti akapo naa ati igbakeji rẹ si ṣe wuruwuru pẹlu owo naa lai fi si ile ifowopamọsi.

EFCC ni Akapo ijọ naa fun igbakeji rẹ ni $ 500,000.

Ile ẹjọ paṣẹ ki Aku da owo naa pada fun ile ijọsin naa ati gbogbo ohun ini ti o ba to iye owo ti o ji naa.

Related Topics