Lebanon: Iṣẹ́ tí kòsí ní Naijiria, la ṣe lọ ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ ní Lebanon

Omolola Ajayi tí orí kóyo ní oko ẹru Lebanon ti kesi ijọba lorilẹede Naijiria lati pese iṣe fun awọn ọdọ lorilẹ-ede Naijiria nitori awọn ni wọn n lo fi ṣe owo ẹru lorilẹede naa.

Ajayi sọ eyi fun BBC Yoruba ni kete to de si ilu Ilorin lẹyin ti ijọba mu pada lati orilẹede Lebanon nibi to ti lọ ṣe iṣẹ ẹru.

Laipẹ yii ni ni ori ko Omolola Ajayi yọ l'oko ẹru Lebanon, lẹyin to fi fidio kan lede leyi to gba oju opo Facebook kan.

Obinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ọhun ni ori ko yọ, lẹyin to figbe ta lori itakun agbaye, to si ṣalaye ohun toju rẹ ri lorilẹ-ede ọhun.

Ajayi ni iṣẹ ti awọn lọ n ṣe ni lẹra fun awọn, ti ọpọlọpọ si n ṣe aisan lai si itọju rara fun wọn.

O ke si ijọba wi pe ki wọn ran ọdọ lọwọ nipa pipese iṣẹ fun awọn obinrin, nitori ai si isẹ lo mu wọn lọ ma a ṣe ọmọ ọdọ ni Lebanon.

Arabinrin naa ni wọn ko san owo osu fun wọn lati igba ti wọn ti lọ si ibẹ nitori ko si owo dọla ni lorilẹ-ede Lebanon bayii.

Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria to n gbero ati lọ si Lebanon lati tu ero wọn pa, nitori nnkan ko ri bi wọn ṣe ro.