Amotekun: Nnamdi Kanu ní ètò Amotekun yóò tẹ̀síwájú bí ìjọba fẹ́, bó kọ̀

Nnamdi Kanu Image copyright Twitter/Nnamdi Kanu

Olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu naa ti da si ọrọ ''Operation Amọtẹkun'' ti ijọba sọ pe ifilọlẹ rẹ ko ba ofin mu.

Kanu ṣalaye pe gbọingbọin lẹgbẹ IPOB wa lẹyin awọn gomina ipinlẹ Yoruba lori ọrọ Amọtẹkun.

O ni Amọtẹkun yoo fidi mulẹ ni, bi ijọba apapọ ba fẹ, bo ba kọ.

Kanu fikun ọrọ rẹ pe, lai fi ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin laarin Yoruba ati Igbo, o ni ẹgbẹ IPOB ṣetan lati fọwọ sowọpọ pẹlu Yoruba.

O ṣalaye siwaju pe, oun ṣetan lati fi miliọnu kan eeyan silẹ fun eto naa gẹgẹ bi iranwọ lati ọdọ oun ti wọn ba nilo iru iranlọwọ bẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, lẹyin ifilọlẹ eto Amotekun niluu Ibadan, ni Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami kede pe ko si ofin orilẹede Naijiria kankan to ti idasilẹ Amọtẹkun lẹyin.

Ìyàtọ̀ wo ló wà láàrin Amotekun àtàwọn àjọ aláábò mìíràn

Lati igba ti awọn gomina ni ẹkun Iwọ oorun Gusu Naijiria ti ṣe ifilọlẹ ajọ eto aabo ẹkun naa ti wọn pe ni Amọtẹkun, ni awọn ọmọ Naijria kan ti tako o.

Koda, agbẹjọro agba to tun jẹ minisita fun eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami sọ pe igbesẹ awọn gomina naa ko ba ofin mu, nitori ko si ofin to faaye gba ajọ eleto aabo ẹkùn(regional) ni Naijiria.

Image copyright Twitter

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn darandaran ni Naijiria, Miyetti Allah naa sọrọ tako igbesẹ yii.

Ọpọ eniyan, paapa awọn eniyan ilẹ Yoruba lo ti n sọ pe ọrọ ti Malami sọ ko tọ rara. Awọn kan ni "kilode ti ijọba yoo fi sọ pe idasilẹ Amotẹkun nilẹ Yoruba ko ba ofin mu, nigba ti iru ajọ eleto aabo bẹ wa ni ẹkùn Ariwa Naijiria.

Wọn ni "ko si nkan to buru ninu ki ilẹ Yoruba o daabo bo ara rẹ lọwọ awọn Fulani darandaran".

Awọn kan tilẹ n sọ wi pe ọna lati fi aaye gba awọn Fulani daran-daran lati ma pa ẹya Yoruba nipakupa mọ ni igbesẹ ijọba apapọ.

Wọn tọka si awọn 'ajọ eleto aabo' bi awọn ọlọpaa Sharia(Hisbah) to wa ni ipinlẹ Kano, wọn tọka si ikọ eto aabo Civilian Joint Task Force (JTF) to wa ni awọn agbegbe ti Boko Haram n yọ lẹnu ati bẹẹbẹ lọ.

Lori ọrọ yii bakan naa, gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde bẹ aarẹ nigba kan fun Naijiria, Olusegun Obasanjo wo lati jiroro lori iha i ijọba apapọ kọ si idasilẹ Amọtẹkun.

Koda, iroyin sọ pe awọn gomina ilẹ Yoruba yoo ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari nitori ọrọ naa.

Alaga ẹgbẹ awọn gomina , to tun jẹ gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ṣalaye pe wọn da Amẹtẹkun silẹ lati le fi ọkan awọn eniyan ilẹ Yoruba balẹ lori eto aabo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'A rí wàhálà táwọn èèyàn ń kojú nilẹ̀ẹ̀ Yorùbá la ṣe fi "Amotekun" fi ọkàn wọn balẹ̀'

Iyatọ Amọtẹkun si awọn ajọ to ku

Ṣugbọn ṣa, ohun ti a le tọka si ni pe Amọtẹkun nikan ṣi ni ajọ eleto aabo ẹkùn to wa ni Naijiria lọwọlọwọ.

Amọtẹkun yatọ si ajọ eleto aabo ti awọn ipinlẹ ni kaakiri tabi agbegbe.

Fun apẹẹrẹ, awọn ipinlẹ bi Oyo ni ajọ eleto aabo 'Operation Burst'; ipinlẹ Eko naa ni ajọ 'Lagos Neighbourhood Safety Corps (LNSC)' to wa fun amojuto eto aabo ati ifimufinlẹ nipinlẹ Eko.

Nigba kan ri, gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose naa ṣe eto kan lati maa lo awọn ọlọdẹ ibilẹ ' lati daabo bo ipinlẹ Ekiti lọwọ ikọlu awọn Fulani daran-daran'.

Awọn araalu kan si ti n sọ pe ki awọn gomina yii gbe idasilẹ Amọtẹkun lọ si iwaju ile aṣofin wọn lati buwọlu, gẹgẹ bi ọna lati ka ijọba apapọ lọwọ ko.