Ìlẹ̀kẹ̀ ìdí mi ló kó mi yọ lọ́wọ́ àwọn afipábánilòpọ̀ ní Lebanon

Ilẹkẹ

Oríṣun àwòrán, @nanbyet

"Mo kan ra ilẹkẹ idi mi fun oge ṣiṣe lasan ni. Ṣugbọn ilẹkẹ yii lo pada gba mi silẹ lọwọ awọn to tan mi lọ si niyan niyan orilẹede Lebanon lati lọ ṣowo ẹru".

Diẹ lara itan ti Gloria Tayelolu Bright ẹni ọdun mẹtalelọgbọn sọ fun awọn oniroyin ree lẹyin to gba itusilẹ pada wale lati orilẹede Lebanon ti wọn tan an lọ ṣe owo ẹru.

Ọmọ ilu Eruku ni ipinlẹ Kwara ni Gloria to si jẹ abiyamọ to ni ọmọkunrin kan ati ọmọbinrin kan to wa yọlẹ gbero lati lọ si Lebanon ko lee ko ọrọ jọ.

Nigba ti wọn fẹ fa a le ajọ to n ri si igbẹjọ awọn ti wọn nko ṣe owo ẹru (NAPTIP) to wa ni ilu Oshogbo lawọn oniroyin ni anfani ati fi ọrọ wa a lẹnu wo.

BBC Yoruba kan si oniroyin ti Gloria ṣipaya ọrọ yii fun o si fi aridaju han pe bẹẹ gẹlẹ lo ṣe ṣalaye nigba toun ni anfani ati fi ọrọ wa a lẹnu wo.

Àkọlé fídíò,

Lebanon: Iṣẹ́ tí kòsí ní Naijiria, la ṣe lọ ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ ní Lebanon

Dipo ki wọn mu lọ si ileewe kan lati lọ maa ṣe olukọni gẹgẹ bi wn ṣe sọ fun mi ki n to kuro ni Ilorin, ọmọ ọdọ ni wọn n fi mi ṣe.

"Ohun to wa buru ju ninu ọ̀rọ̀ temi ni wi pe, ọga mi bẹrẹ si ni ta omi oge si mi. mo ṣe ohun gbogbo lati le e jina si mi ṣugbọn ṣe lo n kara mọ ọ si i.

Mo ni lati pe e sẹgbẹ lọjọ kan lati jẹ ko m pe ko si ọkunrin mii to le ba mi lajọṣepọ ayafi ẹni to fun mi ni ilẹkẹ idi mi. O bere pe ki ni yoo ṣẹlẹ bi oun ba dan an wo?

Kia ni mo sọ fun un pe ọkunrin to ba ṣe e yoo ya were fun ọjọ mẹfa yo si fo ṣanlẹ ku lọjọ keje. Lara rẹ ba walẹ wọọ fun igba diẹ temi naa si ni alafia".

Gloria ni bayii ni ilẹkẹ idi oun ṣe gba oun silẹ lọwọ ifipabanilopọ. "Ṣugbọn aye mi ri radarada ti mo si nilo lati wa ọna abayọ ki n ma baa ku si ilẹ ajoji.

Ọpẹlọpẹ pe mo ri i pe waya oju opo ayelujara wa ninu ile eyi lo jẹ ki n fi fidio iya to n jẹ mi ranṣẹ ti mo si gbọ pe o tan ka ori ayelujara to bẹẹ ti ajọ Phemic Life Support Foundation ni Ilorin ati olu ileeṣẹ wọn to wa ni Eko ati ilu London wa tu mi silẹ".

Oríṣun àwòrán, @RealAARahman

Ẹwẹ, a gbọ iroyin pe nigba ti ẹjọ naa kan ijọba ipinlẹ Kwara leti, ajọ NSCDC kan lu agbami iṣẹ iwadii ọwọ wọn si ti tẹ awọn afurasi kana: ara orilede Lebanon to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin kan. Wafic Hamze ati agbẹjọro kan, Taofeek Sanusi ti wọn si tun ni o ku Joseph kan to wa loke okun titi di ana, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kinni.

Ijba ipinlẹ Kwara ti fa Gloria le awn obi rẹ lọ́wọ́ ko to di pe aj NAPTIP naa bẹrẹ iṣẹ itẹsiwaju inu iwadii ki wọn to le fi ẹnikẹni jofin.

Gloria ni "mo fẹ gba awọn ọmọ Naijiria mii to ro pe paradise ni lilọ oke okun jẹ ki wọ́n ro o lẹẹmeji ki wọ́n tó kán lù ú".

Àkọlé fídíò,

O leè má mọ̀ bóyá o ní àrùn HIV/AIDS o! Wo àwárí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ yìí