Harry àti Meghan kò ní lo orúkọ oyè wọn mọ́, wọn kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí owó ilú mọ́ ní UK

Image copyright @Karwai
Àkọlé àwòrán Harry àti Meghan kò ní lo orúkọ oyè wọn mọ́, wọn kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí owó ilú mọ́ ní UK

Ile Ọba Buckingham ti fẹnuko lori igbesẹ ọmọọba Harry ati aya rẹ Meghan ti wọn yọ kuro ninu iṣẹ ilu ati tile Ọba.

Awọn mejeeji ko ni maa ṣoju Ọbabinrin Elizabeth nibi kankan mọ.

Omọọba Harry ati Meghan aya rẹ ni awọn pinnu lati da Milionu meji ati irinwo pọun ilẹ Uk ((2.4 million pounds) to jẹ owo ilu ti wọn fi tun ile ti wọn ṣe igbeyawo si iyẹn Frogmore Cottage.

Tọkọtaya yii gba pe pe ile wọn ni Frogmore Cottage ni wọn yoo maa de si ti wọn ba ti wa sile ni UK

Nibẹrẹ asiko ojo lọdun yii ni awọn ofin ati ilana tuntun yii yoo bẹrẹ laarin ọmọọba Harry ati iyawo rẹ pẹlu ile Ọba.

Lẹyin ipade awọn tọkọtaya yii pẹlu Obabinrin Elizabeth ni wọn jọ fẹnuko lori awọn igbesẹ ti yoo jẹ ki lilọ wọn ko rọrun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ọmọ ọdún méjìlà ní mo mọ̀ pé mi ò ní ga'

Obabinrin Elizabeth fi idunnu rẹ han pe awọn ti ọrọ kan gbọ ara wọn ye laisi ikunsinu kankan.

O ni titi aye ni ọmọọmọ oun Harrym aya rẹ ati Archie ọmọ rẹ yoo wa ninu mọlẹbi oun ti oun nifẹ tọkan tọkan.

Bakan naa ni Obabinrin ki awọn mejeeji ku iṣẹ to si ki aya Harry, iyẹn Meghan pe o tete darapọ mọ ile Ọba lẹyin igbeyawo rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn

Akoroyin BBC sile Ọba, Nicholas Witchell salaye pe ọpọ gab pe awọn mejeeji ṣi le pada wa sile ọba lọjọ iwaju.

Tọkọtaya naa ṣeleri fun Ọbabinrin Elizabeth pe awọn ko ni doju ti ile Ọba ninu iwa atii iṣe awọn bi awọn ṣe n ko lọ si oril-eede Canada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Ile Ọba kọ lati sọrọ lori ẹni ti yoo maa pese eto aabo fawọn tọkọtaya yii ati iye owo ti o maa na ijọba lati daabo bo wọn ni Canada.

Itakun agbaye awọn tọkọtaya yii (sussexroyal.com) ni wọn ti ni laipẹ awọn yoo gbe iṣẹ tuntun tọkọtaya sita.

Wọn jọ fẹnuko pe lẹyin ọdunkan awọn ikọ mejeji yoo tun jọ ṣe ipade yẹẹwo boya o ṣi nilo atunṣe sii lọjọ iwaju.