Farmz2U: Irú ajílẹ̀ wo ló yẹ fún lílò lásìkò yìí- Aisha

Farmz2U: Irú ajílẹ̀ wo ló yẹ fún lílò lásìkò yìí- Aisha

Mọ̀ síí nípa ọ̀nà ìgbàlódé tí o fi lè ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ pẹ̀lú èrè- Aishat Raheem

Ayẹ agbẹ, jẹ aye ti Yoruba gba pé aye ajẹrọrun ni nitori pe ìgbẹ́ ni àwọn agba gba pé owo wa.

Ọdọmọbinrin Aisha Ajibola Rahem ṣalaye idi to fi bẹrẹ lilo ẹro igbalode lati pese iranlọwọ fawọn agbẹ lasiko yii.

O mẹnuba ipenija tawọn agbẹ Naijiria n koju ati ọna abayọ nipa lilo "Mobile App' to ṣe fun wọn.

Oludasile Farmz2U ṣalaye kikun lori pataki iṣẹ iwadii lori eso, irufẹ ajilẹ ati iru ilẹdu ti agbẹ n gbin nkan ọgbin si lori ounjẹ wa.

Olamilekan Onabanjo to jẹ ọkan lara awọn agbẹ to n lo Mobile App Farms to You yii ṣalaye irufẹ iranlọwọ ti ẹrọ lọna igbalode yii n ṣe fawọn agbẹ lori ayipada oju ọjọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.