Lassa Fever: Dokíta mẹrin àti àwọn mẹ́tàdinlólogun ti kú ni Kano àti Ondo.

Eku to n fa iba Lassa Image copyright Matthieu Aubry
Àkọlé àwòrán Ekute to n fa iba Lassa pọ ni Iwọ-oorun ilẹ Africa.

Ajọ to n ri si idena ati amojuto arun ni Naijiria, NCDC, ti ṣa akọsilẹ awọn apẹẹrẹ ti aisan iba Lassa to tun ti gbode ni awọn ilu kan ni Naijiria, maa n mu jade lara ẹni to ba ni i.

Ajọ naa sọ pe aisan naa maa n wọpọ ni asiko ẹẹrun nitori bi oju ọjọ ṣe ri.

Ajọ naa tun sọ pe iba Lassa jẹ aisan gboogi to n ba Iwọ-oorun ilẹ Africa finra, ati wi pe Naiiria lo ti maa n pọ ju.

Awọn nkan diẹ ti o le ṣe lati dena iba Lassa

1.Ri i daju pe eku ko si ni ile rẹ.

2.Ma sẹ fi ọwọ rẹ nikan kan eku, boya o ti ku tabi wa laaye.

3.Ma ṣe jẹ ounjẹ tabi eso ti eku ti fi ẹnu kan.

4.Fọ ọwọ rẹ nigba gbogbo pẹlu omi ati ọṣẹ.

5.Maa ko ounjẹ rẹ si inu ike to ni smọri, ko si de daada.

6.Si se ounjẹ rẹ daada ko to o jẹ ni anfaani pupọ.

7.Ri i daju pe ayika rẹ wa ni imọtoto.

8.Ma ṣe fi ara kan ara pẹlu ẹni to ba ni aisan yii.

9.Maa da idọti ile rẹ nu kiakia sinu àgbá ilẹ to ba ni ideri.

10.Ma si ṣe lo oogun ti dokita ko ba kọ fun ọ, o l'ewu.

Apẹẹrẹ ti aisan Lassa maa n fihan lara ẹni to ba ni i

Ara gbígbóná, èébì, ara ríro, àti àwọn àpẹẹrẹ mìrán tí ibà Lassa máá n fihàn

Ninu atẹjade kan ti BBC Yoruba ni anfaani si lori itakun agbaye ajọ naa, fihan pe:

Awọn apẹẹrẹ ati ami ti aisan naa kọkọ maa n fihan kọkọ maa n ri bi ti awọn aisan bi iba.

Awọn apẹẹrẹ naa le jẹ ara gbigbona, ori fifọ, egbo ọna ọfun, ki ara o ma ji pepe, ikọ, eebi, igbẹ gbuuru, ki iṣan ara o maa ro ni, aya didun.

Ṣugbọn to ba ti pẹ lara, awọn apẹẹrẹ naa yo yi si: ki ẹjẹ o maa jade lati imu, oju, eti, ẹnu, oju ara obinrin, iho idi, ati awọn iho miran ninu ara, lai nidii.

Àìsàn Ibà Lassa ti gbẹ̀mi àwọn dókìtà méji àti àwọn ènìyàn mẹ́tàdinlógun mírànn ni ìpínlẹ̀ Kano àti Ondo.

Gomina Akeredolu ti wá rọ àwọn ara ilú láti lọ fi ọkàn wọ́n balẹ̀ ati pe ìjọba ti ṣe awọnn èto láti koju àjàkálẹ̀ ààrun náà.

Ìjọba ìpinlẹ̀ Ondo ni ènìyàn mẹrindínlógun lo ti di olóógbé nípasẹ̀ àìsàn Ibà Lassa nígbà ti ènìyàn mẹ́rìnlélọ́gọ́rin tí ni ifarahàn àìsàn náà.

Bákan náà ni adarí ètò ilèra gbogboogbo ati dídá àisàn dúro ní ilé iṣẹ́ ilera ìpínlẹ̀ Kano Dokìtà Imam Bello, sàlàyé pé àìsàn náà ti pa Dókìtà mẹrin àti ẹnikan ni ilé ìwòsàn ìkọni Aminu Kano.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama

Bakan náà ní ìròyìn ti kan ni ọjọ Ajé tẹ́lẹ̀ pé ènìyàn mẹẹdógun ti jẹ́ ọlọrun nípe nípìnlẹ̀ Ondo nítori àìsàn náà ti o si di mẹ́rìnlélógun ni ọjọ Iṣẹ́gun.

Dókìtà Steven Fagbemi to jẹ́ olúdari dídá ajàkálẹ̀ ààrùn duro sàlàye lọ́jọ́ Iṣẹgun lásìkò to n jábọ fún gómìnà Rotimi Akeredolu àti alága ìjọba ìbílẹ̀ Ondo North àti Central pe ọrọ yii ti n n to apero ọmọ eriwo.

Dokita Steven ni ki awọn ara ilu ṣọra fun gaari ati awọn ounjẹ ti ekute ile le ki ẹnu bọ. nitori pe ekute lo n tan iba Lassa kaakiri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria's Under-19:Ẹ wo bí Ikọ̀ Cricket Naijiria ṣe mi àgbáyé titi

Fagbemi ni Mẹ́rìnlelogun nínú àwọn ènìyàn to ko àìsàn náà ti kú nítori pé ọ̀rọ̀ wọ́n ti de ipele tó lágbara ki wọ́n to gbe wá sí ilé ìwòsàn, èníyàn mẹtadínláàdọta lo ti wa ni ìdádúro bayìí ti wọ́n si n gba ìtọjú nígbà ti àwọn mọkanlelógun ti ni ìmúlárada ti wọ́n si ti lọ ilé wọn.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Lassa Fever: Dokíta mẹrin àti àwọn mẹ́tàdinlólogun ti kú ni Kano àti Ondo.

Gomina Akeredolu ti wá rọ àwọn ara ilú láti lọ fi ọkàn wọ́n balẹ̀ ati pe ìjọba ti ṣe awọnn èto láti koju àjàkálẹ̀ ààrun náà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFarms to You: Irú ajílẹ̀ wo ló yẹ fún lílò lásìkò yìí- Aisha

Bakna náà ní ọ̀ps àwọn alaisan ibà lassa lo ti wa ni yàrá ìtọjú pàjáwìrì ní àwọn ilé ìwòsàn òlùkọni.

Image copyright OTHERS
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ ènìyàn lo ti sọ ẹmi nù nítorí àìsàn Iba Lassa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria's Under-19:Ẹ wo bí Ikọ̀ Cricket Naijiria ṣe mi àgbáyé titi