Olanrewaju Bamidele fi 'Screw driver' gún ìyáwo rẹ̀ pa lo ba gbesin ni bonkẹ́lẹ

Olarewaju

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Olanrewaju Bamidele fi 'Screw driver' gún ìyáwo rẹ̀ pa lo ba gbesin ni bonkẹ́lẹ

Ẹni ogójì ọdún kan Olanrewaju Bamidele to fi Igi lu ìyàwó Adenike rẹ̀ dáku to si fi Screw Driver gun títí tí ẹmi fi bọ́ lẹ́nu rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun ni àwọn ọlọpàá ti fi panpẹ́ si lọ́wọ́.

Ọlọpàá mú ọkùnrin náà lẹ́yìn ti ọmọ olóogbé to jẹ́ ọdún mẹ́ẹ̀dogun, Ayomide mú ẹjọ lọ si àgọ́ ọlọpàá pé ìyá òun àti baba òun ni gbọ́nmi-si-omí-o-to lọ̀rọ̀ ba di ariwo.

Ayomide ní bàbá òun ba la igi mọọ lórí to si fi irinṣe ti wọ́n fi n tú ǹkan (Srew Driver) gun títí ti o fi kú.

Nítori ẹsùn yìí ni ọlọpàá ti ó so mọ ilé iṣẹ́ ọlọpàá eka Ofada níbi tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹlẹ DSP Akinfolahan Oluseye, dari àwọn ènìyànnrẹ lọ si agbègbè Bisọdun ní Ofada láti lọ mú ọkùnrinn náà ti àwọn ara adugbò ti mú lẹ̀ pé kò ni sálọ.

Àkọlé fídíò,

Mobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama

Ìwádiìí ọlọpàá fi hàn pé ọkùnrin náà kò ṣẹ̀ṣẹ̀ maa lu ìyàwó rẹ̀ láti ìgbà de ìgbà

Lẹ́yìn ti ó lu ìyàwó rẹ̀ pa lọ́jọ́ Aikú, o fẹ́ ṣe ni òkú oru láti lọ sín pamọ nígbà ti ọmọ rẹ̀ ri ibi tí o ti n gbẹ́ ilẹ̀ ti yóò sin s, lo wá pariwo ẹgba mí o, èyí ló mu ki àwọn ara ilé sálọ sibẹ̀ ti wọ́n si diìímu ko maa ba sálọ.

Wọ́n ti gbé òkú obinrin náà lọ i ile'ìkóku si ti ilé ìwòsàn ìkọni ti olabisi Onabanjọ ni Sagamu fún àyẹwwò iorú ikú to paa, bákan náà ni wan ti mú igi àti 'Screw Driver' to lo silẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹri.

Àkọlé fídíò,

Farms to You: Irú ajílẹ̀ wo ló yẹ fún lílò lásìkò yìí- Aisha

Kọmísọna ọlọpàá, Kenneth Ebrimson ti pàsẹ pé ki wọ́n mu ọdaran náà ránṣẹ́ si ẹka ìwádìí ìwà ọdaran fún ìwádìí àti igbẹ́jọ.