Mobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama

Bunmi Opakunle to jẹ oludasilẹ ile iṣẹ to n fọ ọkọ ati ile, Mobile Wash ba BBC sọrọ lori irinajo aye rẹ ati ohun to sọọ di ẹni to n fọ ọkọ.

O mẹnuba awọn ọmọ iṣẹ to ni lọkunrin ati lobinrin ati awọn ipenija wọn.

Bunmi Opakunle ti ọpọ maa n pe ni 'slay Mama' gba awọn ọdọ Naijiria ni imọran lati ma ro pe oke okun nikan ni ayọ wa bikoṣe pe ki wọn fi ọwọ ara wọn ṣiṣẹ\aje bi o ti yẹ.

Slay Mama sọ bo ṣe n ṣiṣẹ alase ounjẹ pẹlu ọkọ ati ile fifọ nitori pe ọna kan ko wọ ọja nigabgbọ awọn baba nla Yoruba.