APC Oyo: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní wọ́n ti sin oku aṣàájú olóṣèlú náà lọ́sàn-án Ọjọ́bọ

Oloogbe babatunde Oreitan

Oríṣun àwòrán, @eazyfeeds

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi ba ikọ BBC Yoruba sọrọ lori ipapoda aṣoju pataki kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Babatunde Oreitan.

Oreitan ni wọn dede ba oku rẹ ninu agbara ẹjẹ lọsan Ọjọru, ninu ile rẹ to n bẹ ni agbegbe Ọrẹmeji ni ilu Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lodi si iroyin to n ja rainrain wi pe awọn agbebọn kan lo ṣekupa Oreitan lasiko to n kirun lọwọ ninu ile rẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣalaye fun ikọ BBC Yoruba pe, ibọn kọ ni wọn fi gba ẹmi oloogbe naa.

O ni abẹ ti o mu ni wọn fi ge iṣan ọrun ọwọ ati iṣan ẹsẹ oloogbe naa, eyi to mu ko padanu ọpọlọpọ ẹjẹ ki ọlọjọ to de, amọ̀ iṣẹ iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ agbọgbarimu naa.

Àkọlé fídíò,

Kí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì!

Oríṣun àwòrán, @deeduke1

Bakan naa ni ọkan lara awọn alabaṣiṣẹpọ oloogbe, Mikail Adeleye sọ fun ikọ BBC Yoruba wi pe, oun ati ẹnikan ni awọn jọ wa oloogbe wa si ile rẹ lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Ibi ti wọn si ti n wa Alhaja Oreitan kiri inu ile ni wọn ti dede kan an ninu agbara ẹjẹ.

Oríṣun àwòrán, @NPF

Bo tilẹ jẹ wi pe wọn ti bo aṣiri oku oloogbe ni nnkan bii aago meji ọsan Ọjọbọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti jẹjẹ lati ṣe awari awọn ika eniyan to ṣiṣẹ laabi naa.

Àwọn agbébọn pa olóyè ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo sínu ilé

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria

Ọkan lara awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC kan ni ipinlẹ Oyo ni wọn ti pa si ile rẹ lẹyin akoko irun ẹsin musulumi to ṣe.

Lẹyin irun Duri to lọ ki ni Mọṣalaṣi kan to wa lẹba ile rẹ ni Alhaji Babatunde Oreitan pada sile tawọn ẹni ibi naa si wọle tọ ọ wa.

Igbakeji adari awọn ọdọ ninu ẹgbẹ naa, Afeez Mobolaji Repete lo fi aridaju iṣẹlẹ naa han pe wọn pa ọkan lara awọn adari ẹgbẹ All Progressives Congress ni ipinlẹ Oyo.

Olugbaninimọran pataki tẹlẹ fun gomina ana ti ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi ni Mobolaji Repete to fi aridaju iṣẹlẹ naa han.

Iṣẹlẹ iṣekupa Alhaji Babatunde Oreitan to ṣẹlẹ lọsan ọjọru ọsẹ lo ti da ibanujẹ si ọkan awọn ọmọ ẹgbẹ.

Oloogbe yii jẹ ọkan lara awọn adari ẹgbẹ ni ẹkun Ọna Ara ni ipinlẹ naa nibi ti awọn agbebọn ti ya wọ ile rẹ ti wọn si gba ẹmi rẹ ni agbegbe Oremeji Agugu ilu Ibadan olu ilu ipinlẹ Oyo.

Bo tilẹ jẹ wi pe ko tii si alaye kikun nipa iku rẹ tori akitiyan awọn oniroyin lati ri Ọlọpaa ba sọrọ ko tii yọri si rere.

Àkọlé fídíò,

Láì rọ lápa rọ lẹ́sẹ̀, ẹ wo ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń lọ́ ara lóríṣi ọ̀nà