Cisse ní kí òun dóòlà fóònu rẹ̀ ló bá kó sí Kàǹga ní Mushin

Kanga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Cisse ni ki òun dóòlà fóònu rẹ lo bá kó si Kanga ni Mushin

Ẹní ọdun mẹrindinlọ́gbọ̀n kan ní ojúlé kéjé òpópónà Olanrewaju ni àgbègbè Mohan ni Mushin Ipinlẹ Eko lo ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítori pé o fẹ́ dóòlà foonu rẹ to ko si kanga lójiji.

Iròyìn sọ pé fóònù náà ko ju ẹgbẹ̀run mẹta lọ.

Àwọn ti ọ̀rọ̀ ṣojú wọ́n sàlàye pé Cisse jòkó si etí kanga nígbà ti fóónù rẹ̀ já si kanga ṣùgbọ́n ìgbìyànjú rẹ̀ láti mu fóònù náà lo ba bẹ́ si Kanga ti ko si jáde pada láàyè.

Gẹ́gẹ́ bi Yinka to jẹ ọkàn lára éni ti ọ̀rọ̀ náà ṣoju ṣàlàye fun àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ti wọ́n wá láti yọ ọ kúrò nínú kànga nígbà ti wọ́n de ìbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe sọ, "nígbà ti wọn yóò fi ri Cisse yọ, ọlọjọ ti dé".

Nínú fọ́ran tí o so mọ ìṣẹ̀lẹ̀ to wà ni ìgbòrò ni a ti ri àwọn pánapana àti àwọn ara adúgbò níbi ti wọ́n ti n gbìyànju lati yọ ọkùnrin náà jáde.

Lasìkò to n fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀, Alákoso ilé iṣẹ́ pánapana ni ìpínlẹ̀ Eko Margaret Adeseye sàlàye pe òkú Cisse ni àwọn gbé jáde ti àwon si ti fi lé àwọn ọlọpàá ẹka Olosan lọ́wọ́.

Àkọlé fídíò,

Kí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì!