Coronavirus: Ṣé ó leè tẹ̀lé ọjà Chinco wọ Nàìjíríà?

Awọn eeyan to lo ibomu ni ilu Beijing lorilẹede China

Oríṣun àwòrán, EPAWU HONG

Iye eeyan to ku latari arun Coronavirus lorilẹede China ti di mọkanlelogoji bayii lonii tii ṣe ọjọ kini, oṣu kini ọdun tuntun year 2020.

Lọjọ abamẹta ni eeyan mẹẹdogunni ẹkun Hubei nibi ti arun naa ti kọkọ suyọ ni wọn tun kede pe o ku.

Awọn oṣiṣẹ eleto ilera n lakaka lati pinwọ itankalẹ arun yii tori ọgọọrọ eniyan lo n rinrinajo fun ayẹyẹ ọdun tuntun eyi to jẹ kan pataki ninu iwe kajọ kaṣu wọn.

Fun apẹrẹ, arun yii si ti wa ran de ilẹ Yuroopu nibi ti wọn ti ri aridaju pe eeyan mẹta ti ko o ni ilẹ Faranse. Ilẹ UK ti n ṣewadi awọn kan ti wọn fura pe wọn ko arun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lafikun, awọn oṣiṣẹ ilera naa ti n gbiyanju lati tọpinpin awọn bii ẹgbrun meji to ti ba ọkọ baalu wọ UK lati ilu Hubei, China.

Australia naa ko gbẹyin tori wọn ti ri aridaju ọpọ eeyan to ko arun yii ni Melbourne ati ni Sydney.

Arun yii gangan bẹrẹ ninu ọja kan ti wọ́n ti n ta ounjẹ ni Wuhan ti awọn kan si ti n ta awọn ẹranko buburu lodi si ofin.

Ẹwẹ, awọn akọroyin nipa sayẹnsi ati ilera ti BBC kan, Michelle Roberts ati James Gallagher dahun si ọpọ ibeere ti ẹ le ni lọkan nipa arun naa.

Se o ṣeeṣe ki wọn gbe arun naa wọ inu awọn ọja ti wọn n ra lati Wuhan wa si Naijiria?

Bi o tilẹ jẹ pe ibeere ọhun gangan ni pe ṣe arun yii lee wọ ilẹ UK, ṣugbọn idahun rẹ naa ba Naijiria lara mu.

Ko si idaniloju pe o lee ṣẹlẹ. Awọn ẹya arun to n jẹ Cold Virus ti kan lara wọn jẹ coronavirus kii ye kọja wakati mẹrinlelogun nita agọ ara eniyan.

Ohun to ṣe pabambari ni pe ki eeyan to lee ko coronavirus, ni naa gbudọ ti fi ara kan ẹlomii to ni i tẹlẹ bii mọlẹbi tabi ẹni to n ṣiṣ nile iwosan - ki arun naa to tan kalẹ.

Sé idi kankan wa to fi jẹ pe China ni arun naa ti bẹrẹ?

Bẹẹ ni. Ọpọlọpọ lo n gbe ni tosi ibi to jẹ pe awọn ẹranko wa ni China. Ara ẹranko si ni arun naa ti bẹrẹ ti awọn eeyan tilẹ n ro pe ejo ni o fa a. Ajakalẹ arun SARS atawọn mii bi coronavirus yii ni wọn ko latara adan ati ẹya olongbo kan.

Ni ti arun yii, wọn ṣawari pe arun eleyii ọja ti wọn ti n ta awọn nkan odo atẹranko igbo to fi mọ adiyẹ ati ejo lo ti wa.

Laarin ọjọ diẹ si ni ẹni to ba ko yoo ti maa fi apẹrẹ rẹ han lara.

Àkọlé fídíò,

Mercy Aigbe, Lateef Adedimeji, Ayoola Ayolola kó sọ́wọ́ ìbéèrè kàbìtì, ó di gbọin!!!

Ṣe o ṣeeṣe ki ẹni to ririnajo lọ si China laarin oṣu kẹwaa si ikejila ọdun 2019 ti ko o?

Fun iru arun yii, laarin ọjọ diẹ ni apẹrẹ rẹ fi maa n han lara.

Ṣe itọju wa fun arun yii?

Ko si itọju kankan. Ko si si ohun pupọ ti eeyan le ṣe ju ki eeyan ni imọtoto ara lati din anfani kiko o ku.

Ṣe o ṣeeṣe keeyan gba abẹrẹ ajẹsara ko ma baa ko arun naa?

Ni bayii, ko si abẹrẹ ajẹsara kankan ṣugbọn awọn aṣewadii ti n gbiyanju lati ṣe agbejade ọkan.

Ẹwẹ, ni lọọlọ yii, orilẹede China ti n sare kọ ile iwosan pataki kan ni Wuhan ti wọn yoo ti maa ṣetọju awọn alaisan to ti ko coronavirus.

Wọn n kọ hsibitu naa ni eyi to lee gba ibusun alaisan ẹgbrun kan bẹẹ si ni wọn ni yoo pari, wọn yoo si ṣi i lọjọ kẹta oṣu keji.