Bàbá Leah Sharibu ti fẹ̀si lorí ìròyìn pe ọmọ rẹ ti bímọ fún ọga Boko Haram

Sharibu

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Bàbá Leah Sharibu ti fẹ̀si lorí ìròyìn pe ọmọ rẹ ti bímọ fún ọga Boko Haram

Bàbá Leah Sharibu ọmọbinrin akẹkọ Dapchi to wà ni àhámọ Boko Haram ti fei lori iroyin to gbode pe ọmọ rẹ bimọ fun ọgagun Boko Haram kan.

Laipẹ yi ní ìròyìn ti kò fìdímulẹ̀ kan gbòde pé Leah Sharibu ti bímọ ọkunrin fún adári àwọn ọmọogun Boko Haram àti pé o ti yí pada si ẹsìn Islam.

Nínú ìfọ̀rọwérọ pẹlu Baba Leah èyí ti ilé iroyin Channels ṣe lọjọ Aiku ni ọgbẹ́ni Nathan Sharibu ti sọ pe òun kò ṣetan láti fẹèsì kankan lóri ọ̀rọ̀ náà.

Àkọlé fídíò,

Human trafficking: Iṣẹ́ irun ṣíṣe ló di iṣẹ́ aṣẹ́wó

Baba Leah ni ǹkan to ṣe pàtàkì fú òun ni pé kí òun ri ọmọ òun ki o pàda wále láyọ àti aláfíà ti yóò sì ri bẹ́ẹ̀ àti pé òun ko ni gba ìròyìn òfégè kankan láàyè.

Oniroyin Ahmed Sakilda naa da si ọrọ yi nigba ti o sọ sóri àtẹjiṣẹ́ twitter rẹ̀ pé Leah ti di ìyàwó àdari àwọn Boko Haram àti pé o ti bímọ tuntun jòjòló.

Oríṣun àwòrán, Ahmad@twitter

Àkọlé àwòrán,

Bàbá Leah Sharibu ti fẹ̀si lorí ìròyìn pe ọmọ rẹ ti bímọ fún ọga Boko Haram

Ti ẹ o bá gbàgbé wọn ji Leah àti àwọn ọgọrun akẹgbẹ rẹ gbé ni ilé ìwé wọ́n ni Science Secondary School Dapchi ìpínlẹ Yobe ni ọjọ kọkàndinlógun, ọdun 2018.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pada tú àwọn tókù sílẹ̀ wọn ko fi òun silẹ̀ nítori pe wọn ni o kọ láti kọ ẹsìn Kristeni.

Awọn ẹgbẹ ọmọlẹ́yìn Kristeni àti àwọn ajáfẹ́tọ ọmọniyan jákejádò àgbáye lo ti n polongo fun ìtúsilẹ̀ rẹ̀.