Kobe Bryant: Ọjọ́ pẹ́ tí ìjàmba ọkọ̀ òfurufu ti ń dá ẹ̀mí àwọn èèkàn àgbáyé légbodò

Aworan awọn to ba ijamba ọkọ ofurufu lọ

Awaiye iku o si, ọna ti onikaluku yoo gba lọ le yatọ ṣugbọn ohun to daju ni pe, gbogbo wa la maa ku.

Boya ẹyin naa ti ka iroyin to fọwọ kan eeyan lẹmi nipa iku ilumọọka elere bọọlu alapẹrẹ ọmọ ilẹ Amẹrika, Kobe Bryant, ti o waye ni ọjọ Aiku.

Bryant, ọmọ rẹ obinrin ati awọn meje miran lo ba iṣẹlẹ ijamba ọkọ ẹlikọpta to ja.

Igba akọkọ kọ niyi ti irufẹ ijamba ọkọ baalu ofurufu tabi ẹlikọpta yoo mẹmi awọn ilumọọka lọ.

Ẹ jẹ ki a ṣe ayẹwo awọ́n to ba iru iku bayi lọ:

Samora Machel:

Aarẹ akọkọ ilẹ Mozambique ni Machel n ṣe.

Lọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹwa ọdun 1986 lo si padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ ofurufu to waye nigba ti baalu rẹ ja lẹba bode Mozambique pẹlu South Africa.

Oríṣun àwòrán, AFP

Ẹni ọdun mẹtalelaadọta nii ṣe nigba tọlọjọ de.

Oun ati eeyan mẹtalelọgbọn ni wọn ku ninu ijamba naa. Awọn mẹsan to joko sẹyin baalu naa moribọ ninu ijamba ọhun.

Aaliyah:

Akọrin takasufe ọmọ ilẹ Amẹerika nii Aaliyah ti orukọ rẹ gangan n jẹ Aaliyah Dana Haughton, o si naa wa lara awọn to ba iṣẹlẹ ijamba ọkọ baalu lọ.

Lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2001 ni ọlọjọ mu oun ati awọn mẹjọ miran lọ nigba ti baalu wọn ja ni Bahamas.

Iwaadi fi han pe awakọ baalu naa, Luis Morales III ko ti gbawe aṣẹ lati le wa baalu, ti wọn si tun ri apẹrẹ ogun oloro cocaine ati ọti ninu ẹjẹ rẹ .

Kani pe Aliyah wa laye loni, ko ba pe ogoji ọdun.

Pius Adesanmi:

Ni agbo awọn ọmọwe ni Naijiria, Pius Adesanmi ni ọpọ lero wi pe yoo jogun ọmọwe Wole Soyinka ṣugbọn iku ko jẹ.

Ni ọjọ kẹwa oṣu Kẹta ọdun 2019 ni ibanuje dori awọn ọmọ Naijiria kodo nigbati wọn gbọ ikede pe, ọkọ baalu Ethiopian Airline to gbera lati Ethiopia, ja lulẹ.

Ninu awọn eeyan mẹ́talelaadọrin to ku ninu ijamba yii ni ọmọwe Pius Adesanmi wa.

Oríṣun àwòrán, Adesanmi

Àkọlé àwòrán,

Gbogbo àwọn tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀jọ̀gbọ́n Adesanmi sàlàyé pé jẹ ẹni ti a n pe ni olùjẹ ọmọ ènìyàn, ẹni to fẹ́ràn ará ìlú ti kìí fi ti ẹya ṣe.

Akọni onimọ litiresọ ede Gẹẹsi yi ko fi igba kan sinmi lati ma fi ọrọ rẹ pe akiyesi awọn alaṣẹ si kudiẹkudiẹ to n ba eto iṣelu.

Ọmọ bibi ilu Isanlu ni Pius Adesanmi jẹ ti o si fi iyawo,iya ati awọn ọmọ silẹ lọ.

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ni lasiko ti o dagbere faye.

Vichai Srivaddhanaprabha:

Ẹgbẹ agbabọọlu Leicester City nilẹ Gẹẹsi wa lara awọn ẹgbẹ to pegede fi wọrọkọ jeka.

Aṣeyọri wọn ko si sẹyin bi baba olowo to ni ẹgbẹ naa ti ṣe gbaruku ti wọn.

O wa ṣeni laanu pe baba olowo ẹgbẹ agbabọọlu naa padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ ofurufu ẹlikọpta, ni kete ti o gbera kuro ni papa iṣere Leicester City lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwa 2018.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni n ṣe ni ẹlikọpta naa n fi lakalaka, to si ja lulẹ, ti o si gbina.

Vichai ati awọn eeyan mẹta ti o wa ninu ọkọ naa pẹlu awakọ baalu ọhun ni wọn padanu ẹmi wọn.

Myles Munroe:

Ajihinrere Myles Munroe jẹ ilumọọka ti ọpọ eeyan si ma fi kan ba iwaasu rẹ bọ.

Ohun ni oludasilẹ ile ijọsin Bahamas Faith Ministries International (BFMI), tio si gba ọpọ ami ẹyẹ fun iṣẹ ajihinrere.

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Myles Munroe ati yawo rẹ wa lara awọn toba ijamba ọkọ baalu rẹ to ja lọ

Iku yọwọ rẹ lawo ninu ijamba ọkọ ofurufu kan to waye lọjọ kẹsan oṣu Kọkanla ọdun 2010.

Munroe, iyawo rẹ ati awọn eeyan mẹsan ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbábọ́ọ́lù alápẹ̀rẹ̀, Kobe Bryant àti ọmọ rẹ̀ dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbajugbaja ọmọ ilẹ Amerika to figbakan gba bọọlu alapẹrẹ (Basket Ball), Kobe Bryant ti jade laye pẹlu ọmọ rẹ, Gianna.

Kobe Bryant to jẹ ẹni ọdun mọkanlegoji ati ọmọ rẹ, ẹni ọdun mẹtala, ni wọn papoda ninu ijamba ọkọ baalu.

Àkọlé fídíò,

Fidio to ṣe afihan ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye

Bryant ati iyawo rẹ ni ọmọbinrin mẹta miran Natalia, Bianca ati Capri.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ẹni ọdún mọ́kànlelógójì ni Kobe Bryant kó tó di pé ọkọ̀ òfúrufú tó wọ̀ jàbọ́ tó sì gbiná.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ni, ọkọ ofurufu naa dun bi ibọn, ko to di wi pe o gbina loke, to si jabọ si ori oke to wa ni ilu Calabasas ni ipinlẹ California, lorilẹede Amerika.

Oríṣun àwòrán, AFP

Adari ile iṣẹ ọlọpaa ni agbeegbe naa, Sheriff Alex Villanueva sọ wi pe ko si ẹni to ye ninu iṣẹlẹ naa.

Sheriff Alex Villanueva ni iwadii fihan wi pe, eniyan mẹsan lo wa ninu ọkọ ofufuru naa, eleyii to tako iroyin to n ja rainrain nilẹ tẹlẹ pe, eniyan mẹfa lo wa ninu ọkọ ofufuru naa.

Àkọlé fídíò,

'Ko si ẹni to ye ninu iṣẹlẹ naa'.

Igba marun un ni Bryant ti gba ami ẹyẹ NBA Champion fun ogun ọdun to fi gba bọọlu fun LA Lakers, ko to di wi pe o fẹyin ti ni Osu Kẹrin, ọdun 2016.

Gbogbo awọn to n gba bọọlu alapẹrẹ lorilẹede Amerika lo duro iṣẹju kan fun akọni to papoda naa.

Bakan naa ni awọn gbajugbaja lawujọ ti bẹrẹ si ni ṣe idaro Bryant to papoda naa lojiji, eleyii ti wọn ni o ya wọn lẹnu.

Ajọ Alami Ẹyẹ Grammy naa ko gbẹyin ninu awọn to ki Bryant pe odi gba o ṣe, pẹlu ọrọ wi pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fun wọn lati gba iroyin iku Bryant naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aarẹ Ilẹ Amerika , Donald Trump, Aarẹ ilẹ Amẹrika tẹlẹri, Barack Obama, Gbajugbaja elere idaraya, Usain Bolt pẹlu gbajugbaja olorin, Rapper Kanye West fi ibanujẹ wọn, amọ wọn tun dupẹ fun iru igbe aye ti Kobe Bryant gbe ko to papoda.

Ọdun 2003 ni ọmọbinrin, ẹni ọdun mọkandinlogun fi ẹsun ifipabaniulopọ kan Bryant, amọ ti o sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun naa. Lẹyin ti ẹjọ naa kuro ile ẹjọ ni Bryant tọrọ idariji lọwọ obinrin naa wi pe oun ko mọ pe ko ri iṣẹlẹ naa bi oun ṣe ri.