Yoruba Films: Bó ṣe ń lọ́ lágbo Yollywood lópin ọ̀sẹ̀ yìí

Awọn oṣere Yollywood

Oríṣun àwòrán, Instagram

Akọ ẹja pataki meji lawọn BBC Yoruba lori bo ṣe n lọ lopin ọsẹ gbe jade lonii.

Lateef Adedimeji

Gbajugbaja ọdọ ni Lateef Adedimeji jẹ laarin awọn oṣere Yollywood bẹẹ si ni ko pẹ to dara pọ mọ awọn oṣere ti iṣẹ rẹ ti bẹrẹ si ni bu yọ.

O ti to ọjọ melo kan to ti n kajọ de ere ori itage tuntun to fẹ gbe jade eyi to pe akọle rẹ ni The Prime Minister's Son.

Ere naa to da lori ọmọ adari ilu to dagba ninu iṣẹ ati iya tori ohun to fa sababi ibi rẹ ni ọpọ eniyan atawọn ololufẹ rẹ naa ti n duro de.

Yemi Solade

Gbogbo ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kini ni ayẹyẹ ọjọ ibi gbajugbaja oṣere, Yemi Solade.

Ara ọtọ ni Solade fi ayẹyẹ ọjọ ibi r ti ọdun yii da gẹgẹ bi o ṣe fọ si ori ayelujara pẹlu oriṣiriṣi fọto rẹ.

Lara awọn ololufẹ rẹ tilẹ ki i pe ọgọta ọdun lo pe loke eepẹ bo tilẹ jẹ pe ọlọjọ ibi funrarẹ ko sọ ọ jade pe ọgọta ọdun loun pe.

O fihan gbangba pe idunu Yemi Solade ko ṣee fi mọra tori ọjọ ibi rẹ. Ṣe ni gbogbo oju opo ayelujara rẹ kun fun awọn fọto oriṣiriṣi to fi "dẹmọ" to tun fi "dupẹ" lọwọ Ọlọrun.

O fi eyi gbe ọwọ adura soke si Ọlọrun o si dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ.

Àkọlé fídíò,

'Ọwọ́ tó bá dilẹ̀ ni èṣù ń bl ní iṣẹ́kíṣẹ́'